Home ÀKỌ̀TUN Ọwọ́ tẹ Sọdiq àtàwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ f’ẹ́ṣùn ìpànìyàn nílùú Esiẹ
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 5 days ago

Ọwọ́ tẹ Sọdiq àtàwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ f’ẹ́ṣùn ìpànìyàn nílùú Esiẹ

Ọwọ́ tẹ Sọdiq àtàwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ f’ẹ́ṣùn ìpànìyàn nílùú Esiẹ

Orẹ Òtítọ́jù

Àkúkúùbì sàn, ó ṣẹ́ ọmọ rádaràda.
Afurasí mẹ́rin lọwọ́ àjọ ààbò ẹni lààbò ìlú, NSCDC, nípìńlẹ̀ Kwara, tẹ̀ fẹ́sùn pé wọ́n pa obìnrin kan, Aishat Sanni, sínú oko nílùú Esiẹ, nìjọba ìbílẹ̀ lrẹpọdun, nípìńlẹ̀ Kwara.
Adams Sodiq, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún; Rasaq Rasheed, ọmọ ọdún mẹ́rindinlógún; Lukman Quadri, ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti Billiamine Qayum, ọmọ ọdún mẹ́rindinlógún,

Atẹjade lati ọwọ Alukoro NSCDC ni Kwara, Babawale Zaid Afọlabi, ni ọjọ keji, oṣu kẹrin, ọdun 2021, ni Alhaji Musa Waziri to jẹ akọwe awọn ẹya Fulani ati Bororo niluu Esiẹ fi iṣẹlẹ naa to ajọ naa leti.

Lasiko iwadii nipa bi Aishat ṣe dawati ni wọn ri oku rẹ ninu oko ti wọn pa a si lọjọ kẹta, oṣu kẹrin, ọdun yii, gbogbo ara rẹ ni wọn ṣa yannayanna to si tun wa nihooho.

O ṣalaye siwaju pe, lasiko tawọn fọrọ wa wọn lẹnu wo, ohun ti wọn sọ ni pe ọkan lara awọn obinrin Bororo naa ji eeṣo kaṣu ninu oko, Sodiq Adams si gbiyanju lati mu un, ṣugbọn o pada sa lọ.

Eyi ni wọn lo mu ki Sọdiq atawọn afurasi mẹta yooku lepa Bororo keji (Aishat) titi ti wọn fi mu u balẹ.

Atẹjade naa ni nigba ti Sọdiq n gbiyanju lati fipa ba obinrin naa laṣepọ niyẹn di eyin mọ apa ati ọrun rẹ, to si ge e jẹ yannayanna.

O ni lasiko tọwọ tẹ Sọdiq, ẹjẹ wa ni gbogbo ara aṣọ to wọ lọjọ iṣẹlẹ naa.

O kadii ọrọ rẹ pe awọn ti gbe ẹjọ naa le ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ lati gbe igbesẹ to ba tun yẹ lori ẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

OTOLORIN YORUBA: Itumo owe ‘Omo go, e ni o ma ku, pelu FIDIO

Okan lara awon owe Yoruba pataki ni ‘Omo go, e ni ko ma ku, kin lo tun n pa omo to j…