Home ÀKỌ̀TUN Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - March 3, 2021

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Orẹ Òtítọ́jù

Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní bí èèyàn bá dákẹ́, ó ṣeéṣe kí ti ara onítọ̀ùn ó bá a dákẹ́ pẹ̀lú.
gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn náà lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn kan àwọn adarí iléeṣẹ́ náà pé wọ́n ń gbé ìgbésẹ̀ láti fa ìsàkóso iléeṣẹ́ náà fún àwọn adarí míràn láì jẹ́ kí wọ́n mọ bó ṣe ń lọ, àti pé wọn kò san àwọn ẹ̀tọ́ kan fún wọn.

Awọn oṣiṣẹ naa gbe oriṣiriṣi akọle lọwọ, eyii ti wọn kọ awọn ẹdun ọkan wọn si, ti wọn si n bere pe ki awọn adari ileeṣẹ ọhun wa ṣalaye fun wọn bi ọjọ ọla wọn yoo ṣe ri ni ileeṣẹ ọhun.

Ni Eko, Ibadan, Akure atawọn ẹka Shoprite miran kaakiri Naijiria ni iwọde naa ti n waye.

Niluu Ibadan, awọn oṣiṣẹ Shoprite to wa nibẹ kọ awọn akọle bii “ọdun marun un si mẹwaa lai si igbega lẹnu iṣẹ, a gbọdọ gba owo wa ki Shoperite to salọ,” ati bẹẹbẹẹ lọ.

Lara awọn akọle ti awọn oṣiṣẹ Shoperite ilu Akure kọ ni pe o ti su wọn ki wọn maa ṣiṣe bi ẹru.

Bẹẹ naa ni wọn sọ pe ko bojumu to ki wọn ṣiṣẹ fun ọdun mẹwaa lai gba owo ajẹmọnu kankan.

Ẹwẹ, nigba to n da si ọrọ naa, alaga awọn oniṣowo ni Dugbe, iyẹn niluu Ibadan, Ọgbẹni Silvanus Obisha ni gbogbo ẹka Shoperite to wa ni Naijiria ni ifẹhonuhan naa ti n waye.

O ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ ọhun ti gbe agagodo si ẹnu ọna Shoperite ni Ibadan ati gbogbo ẹka Shoperite miran ni Naijiria lori ẹtọ wọn ti wọn n bere fun.
bo ṣe sọ, gbogbo akitiyan awọn oṣiṣẹ naa lati ni gbolohun pẹlu awọn alaṣẹ ile itaja igbalode ọhun lo ja si pabo nitori wọn ko ṣetan lati ni ijiroro kankan pẹlu awọn oṣiṣẹ naa.

Ṣaaju ni awọn iroyin kan ti kọkọ sọ pe awọn alaṣẹ ile itaja naa ti bẹrẹ igbesẹ lati fa ileeṣẹ ọhun le awọn alaṣẹ miran lọwọ ninu oṣu Kẹrin ọdun yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Òwe – O̩mo̩ gò̩, e̩ní ko má kùú, ikú kín ló máa paá?

Òwe – O̩mo̩ gò̩, e̩ní ko má kùú, ikú kín ló máa paá? E̩ wo fídíò ìsàlè̩ yí, kí e̩ …