Home ÀKỌ̀TUN Mi ò gba owó oṣù fún ọdún mẹ́jọ mi gẹ́gẹ́ bíi gómìnà Ọ̀sun
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - February 28, 2021

Mi ò gba owó oṣù fún ọdún mẹ́jọ mi gẹ́gẹ́ bíi gómìnà Ọ̀sun

Mi ò gba owó oṣù fún ọdún mẹ́jọ mi gẹ́gẹ́ bíi gómìnà Ọ̀sun

Ọrẹ Òtítọ́jù

Minisita ọrọ abẹle, Ọgbẹni Rauf Aregbesola ti sọ pe oun ko gba owo oṣu fun kankan gbogbo ọdun mẹjọ ti oun fi jẹ gomina ipinlẹ Osun.

Aregbesola lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Sola Fasure fi lede.

Ṣaaju ni iroyin kan ti kọkọ gbode pe Aregbesola gba owo oṣu ọdun mẹjọ ọhun lẹẹkan ṣoṣo ko to kuro lori alefa gẹgẹ bii gomina ipinlẹ.

Fasure ni irọ nla gbaa ni iroyin naa, ati pe Aregbesola fi owo rẹ jin ijọba ipinlẹ Osun ni, ko si gba kobo lasiko to wa lori oye.

Agbẹnusọ Aregbesola ni “ẹ jẹ ki n sọ ni gbangba lẹẹkan sii pe Aregbesola ko gba owo oṣu kankan ni gbogbo akoko to fi jẹ Gomina ipinlẹ Osun.”

“idi ni pe ijọba lo pese ile gbigbe fun un, bakan naa ni wọn fun ni ẹṣọ alabo, ounjẹ ọfẹ atawọn ohun amayedẹrun miran, nitori naa, ko na owo kankan ni apo ara rẹ.”
Fasure tẹsiwaju pe “gbogbo awọn ọmọ Aregbesola ti dagba, wọn si ti pari ile ẹkọ, nitori naa ko nilo lati maa wa owo ọmọ ile iwe mọ, idi ree ti o ṣe fi gbogbo owo to yẹ ko gba jin ijọba ipinlẹ rẹ.

O ṣalaye pe ẹni to kọ iroyin pe Aregbesola gba owo oṣu ọdun mẹjọ lẹẹkan ṣoṣo.
Lẹyin naa lo bu ẹnu ẹtẹ lu iroyin naa, to si sọ pe ẹni to fi ọrọ naa lede kan n wa ọna lati ba orukọ rere Aregbesola jẹ ni.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Òwe – O̩mo̩ gò̩, e̩ní ko má kùú, ikú kín ló máa paá?

Òwe – O̩mo̩ gò̩, e̩ní ko má kùú, ikú kín ló máa paá? E̩ wo fídíò ìsàlè̩ yí, kí e̩ …