Home ÀKỌ̀TUN Ẹ gbaradì fún ọ̀wọ́ngógó epo–IPMAN
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 1 week ago

Ẹ gbaradì fún ọ̀wọ́ngógó epo–IPMAN

Ẹ gbaradì fún ọ̀wọ́ngógó epo–IPMAN

Ọrẹ Òtítọ́jù

Bí ìnira bá pọ̀jù,ìgbín á pòṣé ṣààràṣà.
Ile eṣẹ to n ṣe karakata epo lorilẹede Naijiria, IPMAN ti kesi awọn ọmọ Naijiria lati gbaradi fun ọwọngogo epo bẹntiro

National Operations Controller ẹgbẹ awọn elepo ni Naijiria (IPMAN), Mike Osatuyi lo sọ bẹẹ lasiko to n ba akọ̀ròyìn sọrọ lori iroyin to n kaakiri lori ọwọngogo epo bẹntiro ti awọn araalu n sọrọ nipa ẹ.

Osature ni o kere tan awọn ọmọ Naijiria yoo ma ra epo ni igba Naijiria , abi ko ju bẹẹ lọ

O ni owo epo to gbe owo lori ati owo ilẹ okeere dọla to gbe owo lori lo fa a ti ọwọngogo fi ba epo bẹntiro ni Naijiria.

‘Iye ti dọla ba jẹ ati owo epo rọbi lo n jẹ ki epo wọn nitori naa owo epo ko le din ni igba naira abi ju bẹẹ lọ’

Bakan naa lo fikun wi pe owo ti ijọba ba ri lori epo nitori awọn nikan ni wọn n gbe epo wọle ni wọn fi n ṣe nnkan fun araalu.

Arakunrin Osatuyi ni o da oun loju wi pe gbogbo nnkan ni yoo gbe owo lori nitori epo bẹntiro lo ma n sọ bi ọja yoo ṣe ri lọrilẹede Naijiria.

‘ Owo ti ijọba ṣi n san lori epo bẹntiro bi owo iranwọ ni ọdọọdun fẹrẹ to biliọnu meji naira amọ ko si ninu agbekalẹ eto isuna mọ lorilẹede Naijiria.’

‘Epo bẹntiro ni okun ẹmi ọrọ aje orilẹede Naijiria, owo ti ijọba si fi n ṣe nnkan fun araalu wa lati owo ori epo’

Nitori naa ni o parọwa si araalu lati faragba a, ati pe ki ijọba fi ọgbọn ṣe e nitori o le e da wahala silẹ lorilẹede Naijiria, ti ohun gbogbo ba gbe owo lori.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…