Home ÀKỌ̀TUN Ẹranko igbó bu ìdí obìnrin tó ń ṣe gá lọ́wọ́ jẹ
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 2 weeks ago

Ẹranko igbó bu ìdí obìnrin tó ń ṣe gá lọ́wọ́ jẹ

Ẹranko igbó bu ìdí obìnrin tó ń ṣe gá lọ́wọ́ jẹ

Ọrẹ Òtítọ́jù

Àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní
àrìnfẹsẹ̀sí kìí ṣe ìrìn kìlómítà .
Obinrin kan, Shannon Stevens ti fitara pariwo to o ninu irora bi ẹranko inu igbo kan, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni “bear” ṣe ya bo o to si bu u jẹ nidii.

Ninu igbo ti wọn n pe ni Chilkat Lake bush ni Shannon ti ni koun sare ṣe gaa afi fuu to fo soke o figbe ta foo lẹyin ti ẹranko esi naa bu idi rẹ jẹ.Ṣhannon Stevens ti farapa bayii lẹyin ikọlu ẹranko ọhun

Lẹyin to figbe bọ ẹnu ni aburo arabinrin naa ọkunrin sa jade pẹlu ina tọọṣi lọwọ lati lọ wa ori ẹranko naa latoju iho ṣalanga iyagbẹ.

Arabinrin ti ọrọ kan ọhun sọ fun ile iṣẹ iroyin Associated Press pe lẹyin ti oun, aburo oun ati ọrẹ oun ṣẹṣẹ din nnkan ipanu sausage jẹ ta loun ni ki oun sare wọ ile igbọnsẹ afi ti ẹranko yii bu idi oun so.

Shannon n lo opin ọsẹ pẹlu aburo rẹ, Erik ati ọrẹ rẹ labẹ tampoli kan ni asiko ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Arabinrin Stevens ni o ṣeeṣe ki oju ọgbẹ naa jẹ boya ẹranko naa ge oun leyin jẹ ni tabi eekana.

Ó salaye pé ile igbọnsẹ to maa n wa nita ni o ti ṣẹlẹ

“Kete bi mo ṣe fidi le ori nnkan igbọnsẹ naa ni kinni kan ge mi jẹ ni idi”.

Wọn ti sare gbiyanju lati ṣe itọju akọkọ fun un eyi ti oloyinbo n pe ni “first aid”.

Ẹka ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn ẹranko igbo ni Alaska ni awọn ro o pe ẹranko yii to bu arabinrin Stevens jẹ lee jẹ esi dudu eyi ti ko si wọpọ laarin ẹranko.

Nibayii, arabinrin Stevens ni oun ti kọ ọgbọn, oun yoo si maa la oju oun daadaa bayii, farabalẹ wo inu ile igbọnsẹ ko to gbe idi le e lọjọ iwaju.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…