Àwọn gómínà láti Àríwá Orílẹ̀ yìí banújẹ́ lórí ìjà ẹlẹ́yàmẹ̀yà ní Shasha
Àwọn gómínà láti Àríwá Orílẹ̀ yìí banújẹ́ lórí ìjà ẹlẹ́yàmẹ̀yà ní Shasha
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà ní bí ọ̀rọ̀ nlá kò bá tíì tán, èèyàn nlá kò ní-ín sinmi àròyé.
Àwọn gómìnà láti àríwá Orílẹ̀ yìí ní ìbànújẹ́ ọkàn ló jẹ́ fún àwọn pẹ̀lú ìjà ẹlẹ́yàmẹyà tó wáyé ní ọjà Shasha ní ìlú Ìbàdàn, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Èyí kò ṣẹ̀yìn àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe sí gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣèyí Mákindé lẹ́yìn ìjà ẹlẹ́yàmẹyà tó wáyé ní ọjà Shasha ní ìlú Ìbàdàn.
Àwọn gómìnà náà láti àríwá Nàìjíríà ni gómìnà ìpínlẹ̀ Niger,Abubakar Sanni Bello, Zamfara ,Bello Mohammed Matawalle, gómìnà ìpínlẹ̀ Kano, Abdulahi Umar Ganduje àti gómìnà ìpínlẹ̀ Kebbi,Abubakar Atiku Bagudu.
Àwọn gómìnà náà ṣe ìpàdé pẹ̀lú Ṣèyí Mákindé ní ilé ìjọba ní agbègbè Agodi, ní ìlú Ìbàdàn.
Ẹ̀mí ènìyàn kan lọ sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà níbi tí àríyànjiyàn ti wáyé láàrin Hausa àti Yorùbá, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá sì lọ sí ìkọlù náà.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Sèyí Mákindé ní òun yóó ríi pé àlàáfíà jọba nípìínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tí àwọn á sì ríi pé àwọn tó wùwà ọ̀daràn náà fi ojú winá òfin.
Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.
Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…