Ààrẹ Muhammadu tún ti rìnrìn àjò lọ sí Daura
Ààrẹ Muhammadu tún ti rìnrìn àjò lọ sí Daura
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ààrẹ Buhari Muhammadu tún ti rin ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́rin lọ sí Daura ní ìpínlẹ̀ Katsina tó jẹ́ ìlú abínibí rẹ̀.
Ààrẹ kúrò nílé ìjọba lọjọ́ Ẹtì láti, pápákọ̀ òfurufú Umar Musa Yar’adua ni Gómìnà ìpińlẹ̀ Katsina Aminu Masari ti kíi káàbọ̀.
Ìròyìn sọ pé, Ààrẹ Muhammadu Buhari yóò kópa nínú ìfórúkọsílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) àti fífi hàn dájú pé ọmọ ẹgbẹ́ sì ni wọ́n, ètò yìí ni Ààrẹ ti sọ sáájú pé ó ṣe pàtàkì fún ìṣèjọba àwa ara wa Nàìjíríà.
Ilé iṣẹ́ Ààrẹ nínú àtẹjáde tó fi síta, sàlàyé pé :”lásìkò tí Ààrẹ bá wà ní Daura, yóò se àwọn peju sinbi ètò ìforúkọ sílẹ̀ ẹgbẹ́ APC”
” Ó yẹ kí Ààrẹ Buahri padà dé sí ìlú Abuja ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun tó ń bọ̀”
Bí a kò bá gbàgbé, Ààrẹ Muhamadu Buhari ti rìnrìn àjò lọ sí Daura ní ọjọ́ kọkànla oṣù kejìlá ọdun 2020. Lásìkò yìí ni àwọn jànduku yabo ilé Ẹ̀kọ́ GSSS Kankara ti wọ́n sì jí akẹ́kọ̀ọ́ ọkùnrin ọ̀ọ́dúnrún gbé tí wọ́n sì tú wọn sílẹ̀ padà lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà nínú igbó kan ní ìpínlẹ̀ Zamfara
Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.
Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…