Home ÀKỌ̀TUN Orí kó Sẹ́nátọ̀ Orilowo yọ lọ́wọ́ ikú lọ́jọ́ Àìkú nípìnlẹ̀ ọ̀ṣun
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 10, 2021

Orí kó Sẹ́nátọ̀ Orilowo yọ lọ́wọ́ ikú lọ́jọ́ Àìkú nípìnlẹ̀ ọ̀ṣun

Orí kó Sẹ́nátọ̀ Orilowo yọ lọ́wọ́ ikú lọ́jọ́ Àìkú nípìnlẹ̀ ọ̀ṣun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Sẹ́natọ tó n sojú ẹkùn ìwọ̀-oorùn ìpínlẹ̀ Osun nilé ìgbìmọ̀ asofin àgbà nilùú Abuja Aderele Orilowo bọ́yọ lọ́wọ́ ikú òjijì lọ́jọ́ àìkú.
Ìròyìn sọ pé ń ṣe ìpàdé ẹkùn rẹ̀ nílé ẹgbẹ́ nílùú Ikire nígbà tí àwọn jàgùdà yawọ olú ìlú ìjọba ìbílẹ̀ Irewole ìpínlẹ̀ Ọṣun pẹ̀lú àdá àti kùùmọ̀.
Ọpẹ́lọpẹ́ ẹ̀sọ ààbò tó sọ sẹ́nátọ̀ náà ti kọ́ gba àwọn jàndùkú náà láàyè láti kojú sẹ́nátọ̀ tí tí wọ́n fi gbé sálọ

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, akọ̀wé sẹ́nátọ̀ ọ̀gbẹ́ni Niyi Isamotu sàlàyé pé, àwọn kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣe ìpàdé ẹgbẹ́ APC ní ìlú ìkirè.
Ó ní bótilẹ̀ jẹ́ pé, kò sí ẹni tó farapa, síbẹ̀ gbogbo mótò tó wà ní àyíkà ni wọ́n bàjẹ́ pátá. “Ní kété tí a debẹ̀ ni a ri pé, wàhálà bẹ̀rẹ̀, sùgbọ́n pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ẹ̀sọ́ ààbò, ni wọ́n sáré gbé e sẹ́natọ̀ sálọ kúrò níbẹ̀

Kò tán síbẹ̀, nígbà tí sẹ́natọ̀ náà móríbọ́, ni àwọn jàndùkú náà kó sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó kù níbi ìpàdé òun.
Bákan náà ni sẹ́nátọ̀ ọ̀un kọọ́ sí ojú òpó abẹ́yẹfò facebook rẹ̀ pé, orí kó òun yọ lọ́wọ́ àwọn agbanipa, ògo ni fún Ọlọ́run

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19.

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19. Ọrẹ Òtítọ…