Home ÀKỌ̀TUN Òṣìṣẹ́ Àmọ̀tẹ́kùn kan yìnbọn fún ọlọ́pàá nílùú Ọ̀yọ́
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 4, 2021

Òṣìṣẹ́ Àmọ̀tẹ́kùn kan yìnbọn fún ọlọ́pàá nílùú Ọ̀yọ́

Òṣìṣẹ́ Àmọ̀tẹ́kùn kan yìnbọn fún ọlọ́pàá nílùú Ọ̀yọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ àjọ elétò àbò tiwantiwa, ìyẹn Àmọ̀tẹ́kùn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ibrahim Ogundele ti yìnbọn sí ọlọ́pàá kan ní ìlú Ọ̀yọ́.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ, ikọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn ní agbègbè Ìsàlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni Ogundele wà.

Bákan náà ni Ìròyìn fi kún un pé kọ́sítébù ni ọlọ́pàá tí wọ́n yìnbọn sí náà ní àgọ́ ọlọ́pàá Ojongbodu ní ìlú Ọ̀yọ́, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Fatai Yẹkini.

Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ní ẹsẹ̀ òsì ní ọta ìbọn náà ti bàá tí wọ́n sì ti gbé e lọ sí iléèwòsàn ńlá Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tó wà lágbègbè Owode ní ìlú Ọ̀yọ́.

Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ojú wọn ṣàlàyé pé lásìkò tí àwọn ọlọ́pàá láti àgọ́ ọlọ́pàá Ojongbodu ń gbìyànjú àti tú àwọn ọ̀dọ́ kan tó ń gbaradì àti ṣe àjọ̀dún ọlọ́dọdún un wọn tí a mọ̀ sí Carnival ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19.

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19. Ọrẹ Òtítọ…