Home ÀKỌ̀TUN Gómínà Òǹdó Rótìmí Akérédolú pàdánù amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 3, 2021

Gómínà Òǹdó Rótìmí Akérédolú pàdánù amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀

Gómínà Òǹdó Rótìmí Akérédolú pàdánù amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé ijọ́ tí ẹ̀dá yóó bá sọnù, gá gá lara á yárúuwọn. Bẹ́ẹ̀ ijọ́ a kú làá dère, èèyàn ò sunwọ̀n láàyè.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Òǹdó ti Gómìnà Rótìmí Akérédolú n tukọ̀ rẹ̀ pàdánu Tosin Ogunbodede tó jẹ́ adarí ètò fún un ní ìpińlẹ̀ náà.

Ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ̀ náà wáyé ní òpópónà márosẹ̀ Ilesha sí Àkúrẹ́, nígbà tí Ogunbodede ń bọ̀ láti Ìbàdàn tó ti lọ kí ìbátan rẹ̀.

Gómìnà ìpińlẹ̀ Òǹdó Rótìmí Akérédolú nínú àtẹjáde tí Kọmísọ́nà fún ètò ìròyìn àti ìlànilọ́yẹ̀ fọ́wọ́sí, sàlàye pé ìbánújẹ́ ńla ló jẹ́ láti pàdánù olórí ètò ilé ìjọba òun.

Gómìnà fí kún un pé, òun gan ni òun pàdánù lórí ikú Ogunbodede, sùgbọ́n, ó rọ gbogbo ènìyàn láti gbà pé àmúwá Ọlọ́run ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Nínú àtẹ̀jáde ọ̀hún kọmísọ̀nà náà sàlàyé pé ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà wáye ní ǹnkan bíi aagọ mẹ́jọ kù ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún ní alẹ́ Ọjọ́ Sátidé, ọjọ́ kejì, oṣù kínní ọdún 2021, lópòópónà Ilesha-Akure.

Ìkú òjiji náà wáye lásìkò tó ń bọ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ Ọ̀jọ̀gbọ́n Benjamin Ogunbodede tó ti ṣe àìsàn tipẹ̀ nílùú Ìbàdàn

“Chief Protocol” Tosin Ogunbodede tó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ọ̀wọ̀ ní kọ́mísọnà ni wọ́n yóò gbé òkú rẹ̀ wọ ìlú lónìí, láti se gbogbo ètò tó yẹ lái fi falẹ̀.

Àti òun àti awakọ̀ rẹ̀, ni wọ́n jọ pàdánù ẹ̀mí wọ́n nígbà ti ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ Toyota Corolla wọ́n kó ṣenu ọkọ̀ àjàgbé

Ó ní ọkàn nínú àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ”Chief of Protocol” Tosin Ogunbodede ti jẹ́ Ọlọ́run nípè, nígbà ti èni kejì wá ni ẹsẹ̀ kan ayé, ẹsẹ̀ kan ọ̀run.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ Òǹdó Tee Leo Ikoro papàá fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múll fún akọ̀ròyìn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19.

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19. Ọrẹ Òtítọ…