Home Orisirisi Aare Buhari ranse ikini ibanikedun si ebi Akinwunmi Ishola
Orisirisi - February 18, 2018

Aare Buhari ranse ikini ibanikedun si ebi Akinwunmi Ishola

A bi Akinwunmi Isola ni ilu Ibadan ni odun 1939. O kawe ni Labode Methodist School ati Wesley College Ibadan. O lo Yunifasiti Ibadan nibi to ti kekoo gba oye B’A ninu ede Faranse (French Language. O tun lo yunifasiti Eko nibi ti won ti gba Oye M.A ninu Litireso Yoruba. O je oluko Yunifasiti Obafemi Awolowo, Ile-Ife. Won pada gbaa gege bi Ojogbon ni Obafemi Awolowo Yunifasiti ni odun 1991.Baba yii lo ko orin isokan ti Ile-iwe Wesley College Ibadan lodun 1986.
Ere akoko ti baba ko ni “Efunsetan Aniwura” ni odun 1961 si 1962 nigba ti baba si je akekoo Yunifasiti Ibadan. Leyin eyi ni baba ko iwe “O leku”. Onkowe, Onkotan, Agbasalaruge, Sorosoro ati osere ni baba.
Akinwunmi Ishola kopa ninu ere “Saworo-ide”,”Campus Queen” ati bee bee lo. Baba yii lo ko iwe “Ogun omode, Belly Bellows, Herbert Macaulay and the spirit of Lagos ati bee bee lo.
Lati nnkan bii odun meji bayii ni baba naa ti wa lori aisan agba ki Olojo to de. “Aisan lo see wo, a ko ri ti Olojo se”
Gbogbo tolori telemu lo ti n wo nile Ojogbon naa, lati ori Aare Mohammadu Buhari ni ikini aseyinde eni ire ti n wa.
Ki Eledua ba wa te Ojogbon Akinwunmi Ishola si afefe ire.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo Fẹ́mi Akínṣọlá Ọ̀fọ́n àn tọ̀ sí gbẹ̀gìr…