Home Orisirisi Soyinka fun Buhari ni ebun Valentine to gbona
Orisirisi - February 14, 2018

Soyinka fun Buhari ni ebun Valentine to gbona

Nigba ti opo eniyan n gba ebun bii owo ati aso lasiko ayajo odun awon ololufe yii, ti a mo si Valentine’s Day, Ogbontarigi onimo ati onkowe, Ojogbon Wole Soyinka, ti fun Aare Muhammadu Buhari ni ebun to gbona janjan.
Dipo ti Soyinka iba fi fun Buhari ni ododo tabi ko fun un ni oti waini, o kan ju oko oro si Aso Rock ni.
O so ni ilu Eko pe Buhari ti sun lo fonfon, debi pe oro re dabi ti eni ti ko mo ohun to n lo mo.
Ninu oro apileso kan to pe akole re ni, ‘Nomads and nation: Valentine card or valedictory rites’, Soyinka ni opo nnkan to n sele ninu ijoba Buhari ko see maa gbo.
O ni ti Buhari ko ba ti sun lo ni, ko ye ko maa gba iru re laaye.
O se apere awon Fulani darandaran ti won n da ilu ru kaakiri, ati bi ijoba Buhari tun se gba Akowe Agba fun ajo National Health Insurance Scheme sise pada leyin ti Minisita fun Oro Ilera ti da a duro lori esun iwa ibaje.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo Fẹ́mi Akínṣọlá Ọ̀fọ́n àn tọ̀ sí gbẹ̀gìr…