Home Orisirisi Won fi ambulansi gbe Olisa Metuh lo si kootu
Orisirisi - February 5, 2018

Won fi ambulansi gbe Olisa Metuh lo si kootu

LAL
Nnkan nla sele ni ilu Abuja lonii, nigba ti won fi ambulansi gbe Agbenusu fun Egbe PDP tele, Oloye Olisa Metuh lo si kootu.
O jo pe ori aare nla ni o wa tori ori beedi alaare naa ni won gbe si, ti won si gbe e dilodilo lo si iwaju Adajo Abang Okon.
Loya Metuh ti so fun ile ejo tele pe ara onibara oun ko ya. Sugbon adajo ni dandan, o gbodo yoju si ile ejo, bi bee ko, oun a gbese le beeli re.
Boya adajo ro pe o n se mogomogo ni.
Sugbon nigba ti adajo ri Metuh ti won di bandeeji mo o lorun, ti won n gbe e dilodilo, o ni ki won yara gbe e pada si osibitu.
Inu osu keta lo fi igbejo si.
Metuh n jejo o iwa ibaje, lori esun pe o gba irinwo milionu naira lowo (N400m) lara owo to ye ki ijoba Goodluck Jonathan fi ra ohun ija ogun lati koju Boko Haram.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo Fẹ́mi Akínṣọlá Ọ̀fọ́n àn tọ̀ sí gbẹ̀gìr…