Home Orisirisi Idi ti Kudirat ko se ri owo kankan gba ninu ogun MKO Abiola – Mumuni, omo oloogbe
Orisirisi - February 1, 2018

Idi ti Kudirat ko se ri owo kankan gba ninu ogun MKO Abiola – Mumuni, omo oloogbe

Okan lara awon omo Oloye MKO Abiola, iyen Mumuni, ti se alaye ohun to n fa ija laarin awon ebi oloogbe naa, lori bi won se fe pin ogun re.
Odun 1998 ni MKO jade laye, lasiko to n ja fun ati di Aare Naijiria, gege bi awon eniyan ti dibo fun ni June 12, odun 1993.
Mumuni je okan lara awon omo Alhaja Kudi Abiola, eni ti ijoba Abacha pa ni ipa ika, lasiko ti won n ja ajgbara naa.
Mumuni ni egbon awon Kola ko fun oun laye lati gbe awon dukia baba awon kan to ti n jera mole dide.
O niadie kii ku ki a da eyin re nu, awon ni lati u idagbasoke ba ibi ti baba awon fi aye si ni.
O ni owo ti baba awon ni ki won fun awon egbon ati aburo re, won ti fun won gege bo se wa ninu iwe ipingun o fi sile – iyen will.
O ni won ti pin t’awon iyawo bakan naa, sugbon iya oun ko ri gba nitori pe o ti ku.
O ni ofin ile Geesi ti won fi se iwe ipingun naa ko si fi aaye gba ki won fun awon omo irufe oloogbe naa niohun to to si i.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìjàǹbá ọkọ̀ ní Fìdíwọ́ gbẹ̀mí èèyàn mẹ́fà láàrin ọ̀sẹ̀ kan

Ìjàǹbá ọkọ̀ ní Fìdíwọ́ gbẹ̀mí èèyàn mẹ́fà láàrin ọ̀sẹ̀ kan Ọrẹ Òtítọ́jù À fi kí Ọlọ́run má…