Home ERÉ ÌDÁRAYÁ Asesede Sanchez ko okuta ba Man U
ERÉ ÌDÁRAYÁ - Orisirisi - February 1, 2018

Asesede Sanchez ko okuta ba Man U

Omulemofo ni Sanchez ati Manchester United mu ninu idije akoko to gba pelu won ni ojo Alaruba.
Tottenham se won bi ose see s’oju, nigba to fun won ni ami ayo meji si odo.
Eyi fa a ki adari Man U, Jose Morinho maa wo bi eni ti moto ja sile.
Ki idije naa to waye, Alex SANCHEZ, ti fi orisiirisii akosile ti ko legbe le le ninu itan ere boolu alafesegba ni orileede England. Sanches gbe boolu gbigba re wo ilu England ni nnkan bii odun merin seyin nigba ti ti o darapo mo egbe agbaboolu Arsenal lati inu egbe agbaboolu Barcelona ninu odun 2004.
Nibayii, egbe agbaboolu Manchester United pelu ati fi omo orileede Armenia, Henrikh Mkhitaryan, ti o wa ni odo won paaro lati je ki Alexis Sanchez wa si odo won bo ti le je wipe egbe agbaboolu Manchester City ni o ko ko fi ife han lati ra Sanchez.
Nibayii, Sanchez maa gba owo to to £350,000 ni osoose fun odun merin ati aabo, eyi ti o so Alexis Sanchez di agbaboolu ti o n gba owo ju lo ni orileede England ati wipe oun ni agbaboolu akoko lati orileede Chile ti o ma gba boolu fun iko agba akoko ti egbe agbaboolu Manchester United.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé Ọrẹ Òtítọ́jù Nítorí à…