Home ÀRÒJINLẸ̀ Ijoba apapo ni lati gbajoba pada
ÀRÒJINLẸ̀ - January 27, 2018

Ijoba apapo ni lati gbajoba pada

Gbogbo eyin ololufe arojinle, e ku ojo meta. “Ile aye ko ni le titi ki a lo inu omi lo re kole si nitori pe iran awon eja lo ni inu ibu”. Oro Naijiria, e ma se je ki o su wa.
Atowoda ni isoro wa kii se amuwa Olorun. Nnkan meji ni isoro to n ba egbe oselu APC finra lowo bayii. Awon nnkan mejeeji naa ni oro epo to n fi eni ku fi ola dide ati oro awon Fulani darandaran.
Ki awon nnkan mejeeji yii to lale wu bi owara ojo, a si n ni ireti pe ilu yii si maa dara, sugbon bayii, opo awon eniyan ni o ti so ireti nu ni eyi ti ko ye ki o ri bee.
Oro epo petiro, “oro kanle kan bale, yoo kan jeje ni mo jokoo mi”. Ti epo petiro yii ba ti di owon gogo. Gbogbo omo Naijiria lo n fara gbaa. Yoo kan eni to ni moto, yoo kan eni to n wo moto, yoo kan eni to n gun masinni ati eni ti o n ra nnkan. Gbogbo oloja lo maa ni owo oko to won lo je ki oja naa won gogo bee.
Oro ti awon Fulani darandaran yii lo tun wa buru ju nitori emi ti awon tun n mu lo. Won n je oko run, ti won ba ba oloko nibe, won a paa. Bi ijoba yii se gbiyanju to lori oro ogbin. Awon Fulani darandaran yii wa je ki oro naa da bi igba ti eniyan fowo sise, to wa fese daa nu. Foonu igbalode ti gbogbo eniyan n mu kiri naa wa je ki iroyin buruku maa ran kiri. Gbogbo bi won se n wo oko, ba oko je ti ko si awon eso alaabo ilu kankan ti o kapa won.
Eyi buru de bi wi pe, ko si eebu ti aye bu ijoba yii ti ko se regi mo won lara. Ti o ba je Fulani ni awon eniyan buruku yii loooto, se Aare Buhari ko le pe awon olori won ki o ba won se ipade, ki won si so ede si ara won pe ki won jowo ma se da ilu ru mo oun lori. Abi ki won tun wa lati orileede miran bi awon kan se n so, se ijoba apapo naa ko ri nnkankan se si awon bode to yii Naijiria po ni? Abi ki a ni agbara awon olopaa ko ka awon odaluru yii, kin ni awon soja n se ni Bareke ni igba ti isoro wa ni ilu? Awon ipinle ni awon fe ni olopaa ipinle sugbon ijoba apapo ko fowo sii. Ijoba ni lati gba ijoba re pada. Ohun itiju lo je fun eni to ba loju. Awon ara ilu tun pe akiyesi ijoba apapo si igba ti awon eya kan n beere fun orileede Biafra, won ni ijoba mo bo se segun won. Kin wa lo de to bee ti agbara ijoba apapo ko ka awon Fulani darandaran? Ijoba ni lati gba ijoba re pada nitori pe “akuku joye san ju enu mi ko ka ilu lo”.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìjàǹbá ọkọ̀ ní Fìdíwọ́ gbẹ̀mí èèyàn mẹ́fà láàrin ọ̀sẹ̀ kan

Ìjàǹbá ọkọ̀ ní Fìdíwọ́ gbẹ̀mí èèyàn mẹ́fà láàrin ọ̀sẹ̀ kan Ọrẹ Òtítọ́jù À fi kí Ọlọ́run má…