Home Orisirisi 2019: Obasanjo ni o to gee, ki Buhari pada si Daura
Orisirisi - January 23, 2018

2019: Obasanjo ni o to gee, ki Buhari pada si Daura

Aare Orile-ede yii tele, Oloye Olusegun Obasanjo, ti so fun Aare Muhammadu Buhari pe ko ma dabaa gbigbe apoti ibo ni 2019.
O ni ijoba re ti kuna ati pe ko si nnkan tuntun to tun fe se fun Naijiria mo.
Ninu leta nla kan ti Obasanjo ko si Buhari, o ni ireti awon eniyan lori ijoba Buhari ti ja si pabo.
O ni Buhari n se ojusaju lori bi o se n yan awon eniyan sipo ati bi o se n se lori ija buruku to n sele larin awon Fulani darandaran ati awon agbe.
Obasanjo tun so pe ko si eso rere Kankan ti APC ati PDP le so fun Naijria ni odun 2019.
O wa dabaa ki won gbe ajo kan dide ti yoo ri si bi Naijiria yoo se kuro ninuwahala to wa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo Fẹ́mi Akínṣọlá Ọ̀fọ́n àn tọ̀ sí gbẹ̀gìr…