Home iroyin Iku omo mi lo da aare buruku si mi lara – Salawa Abeni
iroyin - Orisirisi - January 18, 2018

Iku omo mi lo da aare buruku si mi lara – Salawa Abeni

Akorin waka pataki, Alhaja Salawa Abeni, ti se alaye bi aare nla se ba a finra fun odun mefa gbako, to si je pe Olorun ni ko je ki arun naa mu emi re lo.
O ni lopelope Olorun ati lopelope awon eniyan pataki to feran re denu ni ko je ki kinni naa mu emi oun lo.
O ni igba to ya ni arun naa so oun di aro, ti oun ko si le jade nile mo.
Ninu iforowanilenuwo kan pelu oniroyin kemiashefonlovehaven, Salawa royin, o tole la.
O ni aisan naa bere nigba ti omo oun Olanrewaju se alaisi.
O ni edun okan ti adanu naa mu wa lo fa a ti oun ni eje ruru, ti orisiirisii arun wa tibe bere.
O ni lasiko naa, awon ebi ore ati akikanju eniyan bii Asiwaju Bola Tinubu ati iya re, Oloogbe Abibatu Mogaji; Gomina Eko tele, Ogbeni Babatunde Fashola ni won ran oun lowo.
O ni Gomina Akinwunmi Ambode naa si ti se gudugudu meje ati yaaya mefa laye oun lenu igba to de ipo yii.
Salawa ranti pe oloogbe Sikiru Ayinde Barrister naa ko fi oro oun sere nigba ti oju ogun le.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìjàǹbá ọkọ̀ ní Fìdíwọ́ gbẹ̀mí èèyàn mẹ́fà láàrin ọ̀sẹ̀ kan

Ìjàǹbá ọkọ̀ ní Fìdíwọ́ gbẹ̀mí èèyàn mẹ́fà láàrin ọ̀sẹ̀ kan Ọrẹ Òtítọ́jù À fi kí Ọlọ́run má…