Home iroyin ‘Ainitiju lo je ki Naijiria si maa ra epo betiroo nile okeere’
iroyin - January 18, 2018

‘Ainitiju lo je ki Naijiria si maa ra epo betiroo nile okeere’

Awon alagbata ati ijoba apapo si n di buuru funra won
Buhari n woju Dangote fun epo
Oga agba tele ni ile ise epo kan, Oloye Jide Oluwole, ti so pe ainitiju ati iwa omugo lo je ki ijoba Naijiria o si maa ra epo betiro nile okeere.
O ni o seni laanu pe lati odun bii mejidinlogun seyin ti ijoba alagbada ti n ra epo betiro nile okeere, won si tubo n se bee ni.
O ni bawo ni a se n gbe pe orile-ede to ni epo robi ko le maa pese epo betiro, to si wa n raa lati oke okun.
Alagba Oluwole ni, “Kii se oro to ye ki a maa gbo pe Naijiria ko le pese epo lati robi to ni. Nnkan itiju ni laarin awon orileede to ku. Bawo ni ile ise ti a ti fi n fopo, iyen refineries, wa ko se ni le sise laarin bii ogun odun? Ijoba Obasanjo se e ni asepati. Ijoba Yaradua atiJonathan naa se e ni asepati. Buhari naa ti fe lo odun merin bayii, ko si anfaani kan ti a n ri lara awon refineries naa.”
Ni bayii, ijoba apapo ati awon alagbata epo ti a mo si marketers si n yi ara won sebe ati si pooro ni o.
Bee, owon epo ko tii role patapata.
Awon alagbata ni epo ti ajo NNPC n fun awon ko to nnkan. Won tun so pe iye N145 fun jala kan ko seese mo, won n wa afikun owo epo.
Sugbon ijoba Buhari ni oun ko fe fi kun un. Boya ife to ni si omo Naijiria lo fa a ni o, tabi eru ibo to n bo lana lo fa a.
Ni ida keji, awon omo egbe PDP ati awon ajo miiran n so pe ti ijoba ba fi kun owo epo, wahala yoo sele.
Abalobabo nip e a ko tii mo ibi ti a n lo lori oro epo.
Ohun kan ti Aare Muhammadu Buhari tun wa gbokan le ni ile ise fopofopo nla kan ti Alhaji Aliko Dangote n ko lowo ni ilu Eko

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìjàǹbá ọkọ̀ ní Fìdíwọ́ gbẹ̀mí èèyàn mẹ́fà láàrin ọ̀sẹ̀ kan

Ìjàǹbá ọkọ̀ ní Fìdíwọ́ gbẹ̀mí èèyàn mẹ́fà láàrin ọ̀sẹ̀ kan Ọrẹ Òtítọ́jù À fi kí Ọlọ́run má…