Home iroyin Ìfilọ́lẹ̀ ẹgbẹ́ OPC tuntun – Razak Arogundade
iroyin - January 1, 2018

Ìfilọ́lẹ̀ ẹgbẹ́ OPC tuntun – Razak Arogundade

“ Ko sogun mo, ko sote mo” Omi tuntun ti ru, eja tuntun si ti wonu re “ “O to gee, alubata ko gbodo tun maa da orin “ “ Bee sini , adie ko gbodo maa jefun ara won mo” Asiko too ti awon omo ogun ( REFORMED OPC ati awa elegbe Oodua ni wa tokantokan yoo kora jopo, ka so ara wa di osusu owo ti ko lee see se, ki a fi awon adari eletan , odale sile, awon ti won ko ni ife ohun rere si awon omo leyin won, yala omo leyin egbe OPC ti o wa laye tabi awon omo ogun OPC ti o ti subu loju ogun. Ifilole “ OPC NEW ERA “ setan lati tele alakale iwe ofin OPC lari ibeere pepe , lati ja fun eto omo Yoruba nile loko,leyin odi, igbelaruge asa ati ise ati idagbasole Orile Ede Naijeria lapapo” E ma gbagbe eyin eniyan mi wi pe awon Yoruba bo won ni” Agbajo owo laa fi n soya, ajeje owo kan ko gberu dori” E je ka sowo po lati gbe ogo omo Yoruba ati ti Orileede yii de Ebute ogo”.
Eyii ni awon oro iwuri ohun isiti ti o n jade lati enu Olori ati Oludari tuntun COMRADE RAZAK AROGUNDADE ti gbogbo eniyan mo si ( SADAM ) si gbogbo awon omo egbe “OODUA “ ti ko lonka. Lara awon Ori ade ti o wa ni ikale ni Oba Alaketu Ilu Ketu, Baale Ilu Maryland, Asoju Senato Gbenga Asafa, Iyaafin Yetunde Ogunsola, Rose Odila, Awon asoju Iyaloja General, awon oloye lokan-o-jokan, oga awon agbofinro ati awon oniroyin .
Gege bii Oba Ketu ti salaye “ December 12, 2017 ti duro fun rere ati igba otun fun gbogbo omo egbe OODUA PEOPLE CONGRESS NEW ERA ,awon omo Yoruba ati Naijeria lapapo lai si mimi kan ti yoo mii layelaye lase Edumare”.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé Ọrẹ Òtítọ́jù Nítorí à…