Home Orisirisi Lai Muhammed sọ ọdún ìjàkadì di tòótọ́ l’Ọ́fà
Orisirisi - December 31, 2017

Lai Muhammed sọ ọdún ìjàkadì di tòótọ́ l’Ọ́fà

Yoruba bo, won ni “oruko ni ro omo nigba ti oriki n r’oniyan”. Eyi lo se mo ilu Ofa ni ipinle Kwara “ijakadi loro Ofa”, omo ija kan, ija kan ti won ja l’Ofa lojo ojosi, o soju ebe laala, o soju pooro ninu oko, i ba soju oloko, i ba lawon …
Odun ijakadi ti wa ni ilu Ofa lati igba awase sugbon olaju ti fe je ki won gbagbe odun naa. Odun 2012 ni itan tun gbee jade ti won si bere si nii see ni odoodun lati igba naa.
Odun ijakadi ti odun yii bimo ire nitori pe minisita fun iroyin ati asa ni orileede yii, Alhaji Lai Muhammed wa ni ibi odun naa ni ojo satide pelu awon alaba-sise po re. Minisita ki awon omo, ara ati ebi ilu Ofa ku oriire. O ni odun ijakadi naa ti darapo mo awon odun to gbajumo ni orileede yii.
Lai Muhammed salaye idi to fi ki awon ara Ofa ati ipinle Kwara ku oriire, o ni gbogbo igba ni ijoba apapo ati awon British Council maa lowo si idagba-soke ati idanilekoo oloore-koore ni eyi ti awon alamojuto odun ijakadi maa bere si ni janfani re ni odun 2018.
Minisita tun salaye pe iru odun yii naa maa bere si ni pawo wole fun ijoba ipinle ati ijoba apapo nitori pe lati ibi gbogbo ni won ti maa wa darapo mo odun naa.
Yato si Alhaji Lai Muhammed, ara awon eniyan jankan-jankan to tun peju-pese si ibi odun naa naa ni Minisita fun eto ibanisoro, Oloye Adebayo Shittu, Olofa ti ilu Ofa, Oba Mufutau Muhammed-Gbadamosi , Aare Ofa Descendants Union, Alhaji Najeemdeen Usman Yasin ati awon alejo pataki miran.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé Ọrẹ Òtítọ́jù Nítorí à…