Home Orisirisi Muiz Banire ri ojuure Buhari
Orisirisi - December 30, 2017

Muiz Banire ri ojuure Buhari

Ijoba Muhammadu Buhari tun ti fihan pe oun ko ba Dokita Muiz Banire ja rara o.
O se eyi nipa yiyan an ni alaga igbimo ajo to n ri si bi won se n seto awon dukia ijoba kan, iyen Asset Management Corporation of Nigeria.
Egbe APC ti Ipinle Eko ti n ba Banire fa surutu fungba die, nipa bi Banire se n lodi si bi won se seto idibo ijoba ibile won.
O so pe Asiwaju Bola Tinubu lo dari ibo naa bo se wu u.
Oro ibinu to n so lo fa a ti APC ni Mushin ati Eko se so pea won yo o bi eni yo jiga gege bi omo egbe.
Sugbon APC ti Abuja tubo fa Banire mora ni, to si je pe oun ni olubadamoran lori oro ofin fun egbe naa.
Buhari tun wa ti fihan pe oun ko ba Banire nija kankan nipa yiyan an si AMCON.
Lara awon miran ti won yan gege bii alaga fun orisirisii ajo ijoba ni Senito Mamora Olorunnbe, Ogbeni Festus Keyamo ati Alagba Niyi Adebayo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé Ọrẹ Òtítọ́jù Nítorí à…