Home Orisirisi Ija nla be sile ni Facebook lori bi Yusuf omo Buhari se ni ijamba lori alupupu Power Bike
Orisirisi - December 30, 2017

Ija nla be sile ni Facebook lori bi Yusuf omo Buhari se ni ijamba lori alupupu Power Bike


Nigba ti opo eniyan se n ba Aare Muhammadu Buhari kedun lori ijamba ti omokunrin re, Yusuf Buhari, ni lori alupupu igbalode Power Bike, ti won si n gbadura ki Olorun tete mu u lara da, awuyewuye nla ti be sile lori awon ero alatgaba, paapaa Facebook, lori oro naa.
Awon omo Naijiria kan n so pe o ye ki won kaanu Yusuf, nigba ti awon kan n so pe ko pon dandan.
Awon ti won n soro odaju naa so pe Aaare Buhari naa kii saaba ba eniyan kedun ti won ba wa ninu isoro. Awon kan ni ko dara bi Ijoba Buhari ko se je ki ile iwosan to wa ni Aso Rock o nilaari, to je pe osibitu aladani ni won ti n setoju Yusuf. Awon kan si so pe ayo ayoju lo mu ki arakunrin naa maa gun power bike, to si n tun n sare asapajude.
Sugbon sa o, opo omo Naijiria lo n da won lohun pe ailarojinle lo je ki won maa so bee. Won ni oselu buruku ni iru awon to n so bee n fi oro naa se. Won ni Buhari n gbiyanju lotun-un losi, ati pe ohun ti yoo ba sele, ko ni sai sele, to si je pe ofo eniyan kii se elomiran.
Lara awon ti won n soro fitafita lori Facebook lori oro naa ni awon oniroyin ati gbenugbenu bii Ogbeni Bolaji Adebiyi, Ebelo Goodluck ati Temitope Ajayi.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìjàǹbá ọkọ̀ ní Fìdíwọ́ gbẹ̀mí èèyàn mẹ́fà láàrin ọ̀sẹ̀ kan

Ìjàǹbá ọkọ̀ ní Fìdíwọ́ gbẹ̀mí èèyàn mẹ́fà láàrin ọ̀sẹ̀ kan Ọrẹ Òtítọ́jù À fi kí Ọlọ́run má…