Home Orisirisi Àwọn ará ìlú ń wojú ìjọba lórí epo pẹtiró
Orisirisi - December 24, 2017

Àwọn ará ìlú ń wojú ìjọba lórí epo pẹtiró

“Oro bale, kan Baale, yoo kan jeje ni mo jokoo mi” ni oro epo petiro ni orileede Naijiria. Ti epo yii ba ti won, o fere ma si ohun ti kii fowo ba ni ilu yii nitori pe a ti gbeke lee ju.
Epo asiko yii to won wa ni opo omo Naijiria lara, nitori owon gogo gbogbo nnkan. Orileede to sese bo lowo ODA ti epo tun wa won. Inira yii po de bii wi pe awon eniyan fere le maa soro odi si ijoba.
Asiko odun keresi ati odun tuntun ti eleyii tun bo si je ki o nira die. Opo eniyan lo maa n lo irinajo lati lo foju kan ebi, ara ati ojulumo. Opo lo maa n fi ipade tabi ajodun si asiko yii.
Ara ohun to tun bi awon ara ilu ninu ni bi awon elepo si n ti oro naa si ara won lori telifison. Awon NNPC ni a ko le lo epo ti a ni tan lasiko yii. Awon PENGASAN fe yan ise lodi tele ni epo fi fe koko won ki won to so pe awon ko se bee mo, nipa idi eyi , ko ye ki epo won. Awon onimoto to n gbe epo kaakiri ni awon ajo kan ni APAPA Eko ni afi ti awon ba san egberun lona ogun naira ki moto kan to le gbepo jade ninu ogba awon. Ajo DPR n ti ile epo ti o ba l’epo ti ko taa tabi to fi kun owo epo naa.
Gbogbo atotonu yii ni o n run awon omo Naijiria ninu nitori pe ilu yii ni ofin, o si ni olori kaakiri abi kin lo wa de ti onikaluku n se ife inu re?
Awon kan tun ni oro Naijiria dabi “okobo to ni oun le bo abere ni ookun”. Won ni awon Seneto kan kora won jo pe awon fe lo tu ogba awon Customs lati lo wo awon eru to n baje si ibe Iasiko ti inira epo wa ni ilu. Won ni bawo ni oro naa se jo ara won?
Awon ara ilu ti n sun ile-epo bayii lati le ri epo ra. Iye to wu opo ni o si n taa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìjàǹbá ọkọ̀ ní Fìdíwọ́ gbẹ̀mí èèyàn mẹ́fà láàrin ọ̀sẹ̀ kan

Ìjàǹbá ọkọ̀ ní Fìdíwọ́ gbẹ̀mí èèyàn mẹ́fà láàrin ọ̀sẹ̀ kan Ọrẹ Òtítọ́jù À fi kí Ọlọ́run má…