Home iroyin Àwọn Ọlọ́pàá ń wá Alaka lórí ọ̀ràn Badoo
iroyin - December 23, 2017

Àwọn Ọlọ́pàá ń wá Alaka lórí ọ̀ràn Badoo

Alhaji Abayomi Alaka ni awon olopaa ni o ni ejo lati je lori iwa ipaniyan awon egbe okunkun BADOO ti o gbile ni ilu Eko ati agbegbe re ni igba kan.
Egbe Badoo ni iroyin gbee pe won maa n ka awon eniyan mole ti won si maa pa gbogbo won pelu kunmo. Won ni aso inuju funfun ni won maa n fi yi eje ti won si maa lo loo fun oogun owo.
Alhaji Alaka ti o ni ile epo alaka kaakiri Ikorodu ati agbegbe re ni awon olopaa n gbe ti won n ju sile ni inu osu kesan-an odun yii. Won ni Alaka lo ni ile orisa kan ti won lo dawo ni igba ti asiri awon eni ibi naa tu. Alaka ni oun kan ba awon to fe maa se ere ori itage ko ile-orisa naa ni, o ni ko ni eje eniyan ninu rara.
Eyi lo je ki awon olopaa fi sile ti iwadii si n te siwaju lati inu osu kesan-an odun yii titi ana ode yii ti iwadii tun kan Alaka pe owo re ko mo rara, awon si nilo re ni ago awon sugbon won ko mo ibi ti o wa ni o je ki awon olopaa ke gbajare si araye pe awon n waa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé Ọrẹ Òtítọ́jù Nítorí à…