Home iroyin Onísòwò òsèlú ni Fayose – Babatunde Ojudu
iroyin - December 19, 2017

Onísòwò òsèlú ni Fayose – Babatunde Ojudu

Senato Babatunde Ojudu to je Oluba-Aare-damoran pataki lori iroyin ni o n ba awon oniroyin soro lori ero re lati dije du ipo gomina ni ipinle Ekiti ni odun to n bo. Ojudu ni eniyan perete ni oselu ti gomina lowo-lowo ni ipinle Ekiti Oloye Ayodele Fayose n se n jo loju.
O ni oro Fayose da bii ki a maa “fi buredi ko eniyan lobe je”. O ni bii ki o maa da oda si ona oni kilomita kan, ki ariwo si kun gbogbo iwe iroyin, bii ki o se afara igbalode si ona ti ko si sun-keere, fa keere, bii ki o maa ran aso fun awon ara ilu, ki o maa jeun kaakiri buka ati bee bee lo nigba ti o si je owo-osu mejo ti ko san.
Ojudu ni iru aso wo ni eni ti ko ri owo ile-iwe omo re san fe wo to fe duro lorun re. O ni oju ti la ju gbogbo ohun ti Fayose n se yii lo. O ni ti oun ba wole gege bii gomina ni ipinle naa, ayipada gidi yoo wa ni ipinle naa nitori pe oun mo ibi ti bata ti n ta awon ara ilu lese.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé Ọrẹ Òtítọ́jù Nítorí à…