Home iroyin Dùgbẹ̀-dùgbẹ sì ń mì n’ibadan
iroyin - December 19, 2017

Dùgbẹ̀-dùgbẹ sì ń mì n’ibadan

Awon igbimo loba loba koju oro solubadan, awon ojulowo Mogaji nileebadan gbena woju awon igbimo loba loba, Soriki ijagboro larun Ibadan ye ko ja jaagbila de aafin.Bi babalawo ba ti n kigbe efori, kalaisan o ma nireti mo
Iwofa roba lona, o sadura kele kele, pe ori i ba ba oun se, oun a si doba, ko mo pe le ola kan ki i ro koko bi ota nii le. Hun! Dugbe dugbe oro loba loba to n ja ran- in ran- in nileebadan ko ti i je rodo mumi o. A bi okan lara oriki pe ija igboro larun Ibadan lo ran mo o bi ina inu papa, to n jo bula bula, laarin ijoba ipinle Oyo ati Oba Adetunji ni. Bi ko ba wa ri be e, kin lo le mu ki awon Agbaoye ti gomina Abiola Ajimobi gbega sipo oba alade le ri lobe, gaaru owo si Oba Soliu Akanmu Adetunji Aje Ogunguniso Olubadan ileebadan,ti won pe ni baba fun won.
Bi a ko ba gbagbe, a ri i pe , awuye wuye yii waye ni kete ti gomina Abiola Ajimobi ti gbe abajade atunto oye loba loba ti adajo feyinti Boade ati awon omo igbimo sise le lori jade, ti awon Baale kan ati awon Agbaoye bii mejo gba agbega si ipo Oba alade, pelu iwe eri ati opa ase , lati owo gomint Abiola Ajimobi.
Agbega ati atunto yii ti Oba Adetunji lodi si, mu ki gomina Abiola Ajimobi faake kori pe, ko si eni ti o le yi ipinu naa pada. Kabiyesi naa fohun akin pe , eru ko ni i ba ori ko sa wo ikun ati pe ko si iku ti yoo pa agba ti poolo ori i re yoo poora.Oba Adetunji ni igbese atunto loba loba nileebadan naa ko daru debi pe enikan yoo satunto re. Kabiyesi so yanya ilu ifokanbale ni lbadan je, eto oye jije ko mu wahala dani.
Awon Agbaoye ti won ti di oba alade bayii, ni bi ti a Oba Lekan Balogun ti lewaju won soro pe ipade oniroyin , lati so ipinnu won faraye gbo, pe ,ina ti jo dori i koko bayii o ati pe oore ofe kan pere lo ku fun Oba Soliu Akanmu Adetunji Aje Ogunguniso bayii. Won dun ko o ko mo Oba Alayeluwa naa pe, ki o satunse awon igbese won’t laarin ojo mokanlelogun sasiko yii, bi be e ko, o se e se ki awon ye apere mo ori Ade naa nidi. Awon Oba alade ti won fohun sokan pe gbolohun naa lati ri Oba Owolabi Olakulehin, Oba Tajudeen Ajibola, Oba Eddy Oyewole, Oba Lateef Gbadamosi Adebimpe, Oba Amidu Ajibade ati Oba Kola Adegbola.Ero awon eeyan ilu kan lori gbolohun ajanilaya pati tawon igbimo loba loba naa pe jade jo pe ,iromi won to n dun ko o ko mo Oba Alayeluwa yii, onilu won wa nile agbara.Awon kan niwoye won so pe, ko ya awon lenu pe awon igbimo loba loba naa n gbe igbese ati yo kabiyesi, tori pe, won ko nii yaju u won sile, ki enikan re won lule lori esin ti gomina Abiola Ajimobi sese gbe won gun.Bi Gomina ba rowon lagbara depo Oba alade, ti gomina pa pa a si ti teko leti relu Abuja mejo Kabiyesi naa ati gomina nigba kan ri Agbaoye Sinato Rasid Adewolu Ladoja sun Aare Muhammadu Buhari pe won n pagidina akitiyan oun lori eto aabo nipinle Oyo.Awon onwoye naa so pe, ohun elo amuseya fun igbese yiyo Olubadan ileebadan , ni awon igbimo loba loba naa je fun gomina, awon naa si moju, won gbofe e, won ko si ni fe ki ohunkohun da yeepe si gaari ti oloore won fi tawon lore.
Bi awon igun igbimo loba loba niha ti gomina Abiola Ajimobi ti n dun mohuru mohuru pe koba o ma tii yayoju lori apere, be e nigun awon kan ti won pera a won ni ojulowo Mogaji nileebadan, nibi ti a ti ri Alhaji Abass Oloko( Mogaji Oloko),Oloye Abduljelyl Karheem(Mogaji Adanla), Alhaji Moshud Gbolagade( Mogaji Akere) ,Alhaji Waheed Kosoko( Mogaji Onilabu), Alhaji Ademola Oladosu( Mogaji Olasomi), ati Oloye Wale Oladoja( Mogaji Akinsola) ,ti fohun sokan fesi nigbona gbooru pada fawon igbimo loba loba naa pe, ki agba a won o ma soro bi ewe o tori pe, igbese fifun Olubadan ileebadan ni gbedeke, ko yato si biigba ti won mo o mo fe ta adin sori esu. Se yooba si bo, won ni eni ti yoo gba laoroye leti onitoun naa yoo dira.
Yooba ni aye jije gba ogbon, gbogbo oro ko ni a a bi ile ka to mo.Die laamu ninu emu ti esinsin ti po loju e, ko keeyan fokanjua je eran to ku u gifa, konitoun pa pa a o mo ba a kuku aitojo. Iroyin Owuro gbadura pe ibi ti esu tapo si de yii, Kalawurabi o fopin si i, kogun abele ati tabenu, o ma gberomo yoruba lateyin.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé Ọrẹ Òtítọ́jù Nítorí à…