Home ÀRÒJINLẸ̀ Bọ́ọ̀lù manigbàgbé láarin Nàìjíríà àti Brazil
ÀRÒJINLẸ̀ - December 16, 2017

Bọ́ọ̀lù manigbàgbé láarin Nàìjíríà àti Brazil

Ojo ohun naa niyi bi ana, ase loooto ni oro awon agba to ni “iyan ogun odun, a maa jo ni lowo”.
Mo se iranti ere boolu to waye laarin egbe agbaboolu Naijiria ati akegbe won ti orileede Brazil ni ilu Atlanta, ere boolu naa waye ni odun 1996. Gege bi gbogbo wa ti mo pe orileede Brazil ni gbogbo aye mo si oba oniboolu. Won maa n gba boolu bi pe awon ni won seda awon boolu naa ni.
Ere boolu naa bere bi ere bi ija titi di wakati metadinlogorin (77th minutes). Ami ayo si wa ni meta si ookan (3 -1).
Ami ayo yii ko jo opo wa loju, awa kan tile n gbadura ki ami ayo naa ma se ju bee lo. Awon kan n gbadura ki ere boolu naa tete pari ki nina ma baa po ju. Awon kan ti binu pa telifison won. Awon kan n fi oti pa ironu re.
Gbogbo awon iko agbaboolu orileede Brazil to mo boolu gba daadaa lo peju-pese si ori papa naa, awon bii – Carlos, Rivaldo, Bebeto ati Ronaldo.
Ko si eni to mo ise Eledua, Kabiyesi Eledumare ba gbe ise re de. “Esuo ba padi da, o n le aja”. Ni igba ti ere boolu di iseju mejidinlogorin (78th minutes) ni Victor Ikepba ba gba boolu wole Brazil, aago ba yi si 3 -2. Esi yii ba mu ki eegun awon egbe agbaboolu Naijiria le kankan. Awa kan ba n dupe pe nina yi ko tile po mo. Ni igba to di aadorin iseju (90 minutes) geerege ni Kanu Nwankwo ba se ese bi eni n fi boolu sere, lo ba ge Dida to je aso-ojuule awon iko Brazil. Boolu ba di 3-3. Oro wa di boo-le-lo, ki o yago fun iko Brazil. Oro naa wa dabii ala. Ofin igba naa si ni pe ti boolu ba ti je omi ti iko kan si gbodo jawe olubori, ofin ni, iko ti o ba ti koko gba boolu wole alatako (Golden goal) ni o bori ere naa. Iko mejeeji yii si gbodo gbiyanju yii titi ogbon iseju.
Iseju meta ti eyi bere ni Kanu Nwankwo ti alaje re n je “papilo” ba gba boolu wole awon iko Brazil. Ariwo ayo ba so kaakiri orileede Naijiria ni ale ojo naa.
Eyin ebi alarojinle, niwon iba ojo ti odun yii ku ko pari, Eledua ma le se iyanu daadaa ninu aye wa. E je ki a tun ero wa pa ni daadaa. E je ki a tepele mo igbiyanju wa ni ona to daa. E ma se je ki a tilekun ero wa pe odun yii ti tan. A si ni lati gbe igbese ona tooto nitori pe “ko si bi eniyan se fe taja erupe, ti ko ni gba owo okuta”. A ku ipalemo odun, a a ba wa laaye ati laye pelu owo, omo ohun aiku baale oro.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé Ọrẹ Òtítọ́jù Nítorí à…