Home Orisirisi Ọlọ́run lòdì sí ká máa kówójọ níbi ìsọjí – Oníwàásù Agboọlá
Orisirisi - December 10, 2017

Ọlọ́run lòdì sí ká máa kówójọ níbi ìsọjí – Oníwàásù Agboọlá

Lara awon iranse Olorun to nigbagbo ninu iwaasu ijere okan ninu ijo Olorun ode oni ni, Oniwaasu Ebenezer Oludare Agboola je laarin awon Iranse Olorun akoko yii. Nitori bi o se maa n waasu oro Olorun tooto, fun awon ayanfe ninu ijo re, gege bi Olorun se pa a lase fun awon iranse re. Ni opin ose to koja yii ni Oniwaasu Agboola gba alejo akoroyin wa, OLUSEYI ONI lalejo nileejosin re, to pe oruko re ni, Christ Apostolic Church, Hand Of God Miracle Centre (HAGOM), eyi to wa ni adugbo Zone D, Kasumu Estate, lebaa Ojo Ekun, Odo Ona Elewe niluu Ibadan. Lasiko naa lo ti je ko di mimo pe ope loro oun to si nigbeyin lenu ise iranse ti Olorun ti pa a lase foun lati se.
Oniwaasu Agboola, to je omobibi ilu Itaji Ekiti, sugbon to tedo si ilu Ibadan lati sise fun Oluwa je ko di mimo pe, idile onigbagbo paraku ni won ti bi oun lomo ni Ilu Itaji Ekiti. Sugbon isele kan lo sele to je ki oun wa si Ibadan lati gbe pelu egbon iya to bi oun lomo, iyen Oloogbe Micheal Babalola Oyeyemi. Oniwaasu Agboola so pe; baba yii lo fe egbon iya oun, to si tun je agba iranse Olorun ninu Ijo CAC nigba aye re.
Odun mefa ni agba Iranse Olorun naa loun wa ti awon obi oun fi mu oun wa si odo baba naa. O wa fi idi oro re mule pe odun merinlelogbon loun lo pelu baba naa. O tun so pe, odo baba yii ti oun lanfaani ati gbe lo je ki oun mo oro Olorun daadaa, ti ko je ki oun lanfaani lati wu iwa buruku kan nigba ewe. Bakan naa lo je ko di mimo pe baba yii naa lo koko so asotele pe oun yoo sise fun Oluwa.
Ileewe Baptist Primary School, Oke Ado Itaji Community Grammar School ni agba iranse Olorun naa so pe oun ti lo si Ileewe, ki Olorun too fun oun ni oore ofe lati lo sile eko gbogbonise, iyen eyi ti won n pe ni Poli, to wa niluu Ibadan. Sugbon lati lo ni imo kun imo ninu Oro Olorun lo ni oun tun fi lo sile eko Bibeli, iyen CAC Seminary to wa ni Orita Mefa. Odun 1994 lo ni Olorun fi idi ipe ise iranse oun mule, Bakan naa lo tenu mo on ninu oro re pe; Olorun fun oun lebun orin, eyi to maa n mu oun loo korin ni opo ile ijosin pelu duru.
Bakan naa ni Oniwaasu Agboola je ki o di mimo ninu oro re pe, oun sise labe ise iranse Baba R. Adepoju ti Ijo CAC Temitope Revival Centre. Baba yii ni alaga nileejosin naa. Odun 2003 lo si kuro nibe lati darapo mo Ijo Jesus Solution Evangelical Ministry, o loun si tun lo odun meta nibe gege bii Ajihinrere, ki Olorun too da Ijo CAC (Hand of God Miracle Centre sile ni Odun 2006. O so pe opo isipaya loun ti ri ni kete ti oun pari Ileewe, zati pe awon iriri yii lo fihan loun lati da ijo sile, sugbon ti oun ko ko ibi ara si i, nitori ise iranse ko wu oun ni Ibere pepe lati se.
Agboola tun so pe; ikilo ti Olorun fun oun pe ti oun ba ko lati se bi oun Oluwa se pa a lase, oun yoo ya aro tabi ki eya ara oun kan di ibaje. Iranse Olorun yii ni Baba Micheal Oyeyemi ti sun ninu Oluwa ni akoko yii, idi niyi ti oun fi loo ba iranse Olorun; Baba Adepoju fun Itoni- sona, ki ijo naa too bere ni 2006.
Agba Iranse Olorun yii je ko di mimo pe gbogbo Ojo ti awon eeyan ba ti n jeri si ise iyanu lati enu ise iranse oun, lo maa n je ojo idunnu foun nitori opo ise iyanu ni Olorun maa n se lati enu ise iranse oun nigbakugba. O tun so ninu oro re pe, opo ipenija loun ni lenu ise iranse, paapaa awon ipenija to wa lati odo awon iranse Olorun elegbe oun. O tun ni awon ipenija yii lo po ju nitori Olorun gbe otito le oun lowo. Eyi lo je ki opo Iranse Oluwa ni emi Ikorira soun nitori opo lo korira otito.
Iranse Olorun yii ni opo lo maa n lero pe oun maa n gberaga, sugbon eyi ko ri bee rara. O wa yannana oro re siwaju si i pe “Opo lo maa n ro pe ogun la n lo nile ijosin yii, eyi to n mu ki opo awon eeyan maa wa lati wa josin nibi. Oniwaasu Agboola ni eyi maa n je ibanuje okan fun oun nitori awon to n so eyi naa lawon n wo gege bi eeyan Olorun, sugbon iyalenu lo je pe ero buburu yii lo wa ninu won, o si maa n ba mi ninu je, mo si tun maa n beere lowo ara mi pe se eeyan Olorun ni tooto lawon eeyan yii sa? Sugbon lati akoko ti mo ti gbo ohun Oluwa to so pe ki maa n wo ibe mo, ni oro won ko ti jo mi loju.
Bakan naa ni Oniwaasu Agboola tun ni isele kan ti o sele ni igba kan je oun eyi ti oun ko le gbagbe, O ni eni to je baba fun oun ni oun pe fun isoji kan lakoko ti ile ijosin naa se isoji, o ni opo awon eeyan lo wa sibi isoji naa, eyi lo mu ki Baba naa bu owo fun awon ayanfe, egberun lona egberun merin lowo ti baba yii kede fun awon eeyan ki won fi ran irin ajo oun lowo lo siluu Jerusalemu lojo naa. O ni eyi je ohun ibanuje okan fun oun nitori Baba naa ko ba oun so ohunkohun ki o to kede naa fawon omo ijo. O wa fi idi oro re mule pe nibi ti won da owo naa si leyin odun meta ni oun too pase lati je ki ijo gba owo naa lati fi ra moto ayokele fun ikede ihinrere fun ijo Olorun, ti awon si fi owo to ku, kun owo oko naa. O ni Olorun ko fe ki iranse re so omo Ijo di ATM tabi kalokalo, eyi ti iranse Olorun le maa lo lati ni owo lowo. O ni ese ni eyi niwaju Olorun.
Oniwaasu Agboola tun so ninu oro re pe Olorun maa n fun oun ni iran lati toju awon alaini tabi opo lawujo, o ni opo owo ni ijo yi yoo lo lodun yii lati se bi Olorun se pa a lase fun oun lati se ni odun yii. O ni Olorun ni ki awon ra onje ati opolopo ohun eelo fun awon ayafe, ki awon si ta a fun awon eeyan ni owo kekere lati sodun. O so o di mimo pe, awon musulumi ati onigbagbo lo ni oore ofe lati ra onje yii. O wa salaye siwaju si i pe kongo iresi kan yoo je igba naira, N200, adiye yoo je eedegbeta naira, iyen N500, nigba ti aso Ankara naa yoo je eedegbeta naira naa, N500 ti apo Semo kekere oni kilo mewaa, 10kg, yoo je ogorun naira, N100.
Ohun iyalenu lo tun je nigba ti iranse Olorun naa tun je ko di mimo pe otito ni pe iwaasu ijere okan ti sonu ninu opo ijo Olorun, o ni ohun to fa eyi ni pe ikun opo ni won je fun, won ko so oro Olorun mo, o ni, otito ni pe opo gba ipe nitooto sugbon nitori ohun ti a o je, won so ipe nu, sugbon Oniwaasu Agboola ni awon Ajinhinrere si wa ninu Ijo Olorun, sugbon opo awon eke Ajinhinrere lo maa n pa iro orisirisi nitori enu ise iranse Olorun ni a ti n ri awon oruko alaje lonii, eyi ti ko dara. Opo a pe ara re ni Baba Solution se won fun Jesu, Peteru ati awon agbaagba iranse Olorun ni iru awon oruko wonyi nigba tiwon ni? O wa gba awon iranse Olorun elegbe re nimoran lati dekun ati maa kede owo fun awon ayanfe ninu ijo, iwaasu Ihinrere, ati ijere okan lo se koko ninu ijo Olorun gege bi Olorun se ran awa iranse re.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé Ọrẹ Òtítọ́jù Nítorí à…