Home iroyin Ìjọba fẹ̀yìn àwọn oníjìbìtì epo balẹ̀
iroyin - December 6, 2017

Ìjọba fẹ̀yìn àwọn oníjìbìtì epo balẹ̀

Ko si ohun to ni ibere ti kii ni opin ni oro epo Petiro ni ilu Eko ati agbegbe re. Laarin wakati merinlelogun ti epo fi won, inu awon agbeyin-bebo ti dun. Awon elepo kan ti n ti geeti ile epo won ki awon eniyan le maa san owo ki won to wole. Awon kan tile ti ile epo won pa ki won le rii ta ni owon gogo. Awon miran n to oju nosu kan ninu bii mewaa ti won ni.
Eyi ti awon ara ilu ni o tile wa ya awon lenu ju ni ohun to jo ere ori itage ni opopona Eko si Ibadan. Awon ile-epo kan wa nibe ti won ti fere ko igba sile tan. Won ti da awon osise won duro ku eyo kan tabi meji nigba ti awon eniyan ko lati ya iwaju won ra epo. Awon ile-epo ti awon eniyan deye si yii ni won ni won ni aye lara ni asiko isejoba Aare Jonathan. Won ni won n jaye bii oba lori owon epo. Lenu ojo kan ti epo won yii ni won ba tun kogba sita. Oro won wa ye awon eniyan pe ninu isoro nikan ni awon ti le sise.
Ju gbogbo re lo, inu awon ara ilu dun pe ijoba segun awon arije-nidii-madaru yii. Won ni ti epo petiro ba won, o maa n sakoba fun gbogbo nnkan pata ni ilu. Bi ounje se n won ni oko wiwo maa won, bee si ni gbogbo awon nnkan to ku naa maa gbenu soke, paapaa julo ni asiko odun yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé Ọrẹ Òtítọ́jù Nítorí à…