Home Orisirisi Orin Odolaye Aremu ni mo feran ju – Lai Mohammed
Orisirisi - November 29, 2017

Orin Odolaye Aremu ni mo feran ju – Lai Mohammed

Ohun to wu mi ko wu o, to difa fun omo iya meji ti won fi fe iyawo otooto. Gege bee ni oro orin naa ri. Nigba ti awon kan maa so pe orin juju, fuji tabi dundun ati sekere ni awon feran ju, orin dadakuada ni Minisita fun Oro Iroyin ati Asa, Alhaji Lai Mohammed, feran julo.

Koda, orin gbajugbaja onidadakuada, Odolaye Aremu, ni Alhaji Mohammed feran ju.

O so eyi fun IROYIN OWURO lasiko iforowanilenuwo kan.

Gege bi minisita naa se so, Odolaye Aremu je eni kan to ni opolo pupo. O ni ko si bi eiyan yoo se maa gbo orin re ti ko ni ri eko ko, ti ko sit un ni maa rin erin lekookan.

Lai Mohammed ni, “Mo gbadun orin Odolaye Aremu pupo. Ti Odolaye ba gbe oro kale bayii, oluware yoo maa miri ni. Iru re ni awon oloyinbo n pe ni filosofa, iye onimo ijinle ti alarojinle gidi. O tun ni awon orin to maa n mu eniyan lara da, ti eni to ba le rin erin a si maa rin erin arintakiti.

“E je ki n tun fikan kun un: Bi Odolaye Aremu ba ki eniyan, ori eni na a maa dide janin ni.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…