Home Orisirisi Omotola sin Banky W ni gbere ipako loro igbeyawo
Orisirisi - November 22, 2017

Omotola sin Banky W ni gbere ipako loro igbeyawo

Bi Omotola Jalade-Ekeinde ba gba alariya kan nimoran lori oro igbeyawo, o to bee, o ju bee lo.

Idi ni pe o wa lara awon osere ti igbeyawo re kofori-sabpon.

Ti a ba ti mu oun, a tun maa mu Joke Silva ati Joke Jacobs.

Se oro ti Salawa Abeni la fe ro ni, ti Ayo Adesanya abi ti Ini Edo, to je pe gbogbo won ni igbeyawo won dojubole?

Boya iriri Omotola naa lo fa a to fi ti gba Banky W ati iyawo jojolo re, Adesuwa, nimoran lori ohun to le je ki igbeyawo won o tojo.

O ni won ko gbodo je ki orejore to wa laarin won o sonu, bo tile je pe ife okan se pataki.

Omotola ni ki won maa so ero okan won sira won deede, ki won si maa funra won ni owo (respect).

Lakotan, Omotola gba won niyanju pe ki won sora fun ero alatagba Internet ati Social Media. O ni ki won ri i pe kii se gbogbo oun to ba sele ninu ile won ni won n ko sori Facebook, Instagram, Twitter ati bee bee lo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…