Home Orisirisi   Eni Olorun ko pa: Igbeyawo Banky W ati Adesuwa n dagboro ru
Orisirisi - November 20, 2017

  Eni Olorun ko pa: Igbeyawo Banky W ati Adesuwa n dagboro ru

 

Lowolowo yii, igbeyawo akorin pataki, Bankole Wellington, ti gbogbo eniyan mo si Banky W, pelu osere fiimu Adesuwa lo n da igboro ru.

Sugbon eyi ko tumo si pe won n ja nibe tabi pe won n se ohun ti ko dara nibe.

Dipo bee, gbogbo nnkan n se minijojo, to n ro kukukeke ni.

Aso olowo iyebiye, alarabara ati awotunwo ni won n wo, ti opo awon eniyan pataki pataki, paapaa awon gbajumo osere naa si n ba won se ajoyo, awon bii Omotola Jalade-Ekeinde, ti awon naa si n se odun aso.

O ye ki Banky W ko jo, ko si yo. Sebi aipe yii ni Olorun ko o yo ninu ewu arun kansa.

Olorun a fore si igbeyawo won o.

Ki Edumare je ki won ba ara won kale.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…