Home iroyin Ijapa soro lori Robert Mugabe
iroyin - November 15, 2017

Ijapa soro lori Robert Mugabe

 

L’ojo kan ti ijapa n lo ba ana re ni alejo, awon eniyan wa bi i leere pe ojo wo ni yoo pada sile. O ni ojo ti oun ba se aseju, ti oun ba te ni.

Oro Aare orile-ede Zimbabwe tele, Alagba Robert Mugabe, lo mu asamo yii wa.

Okunrin naa ni awon ologun orile-ede naa ti gba danu bayii, ti won si le e kuro ni ijoba.

Eyi waye leyin to ti lo ogoji odun lori aga!

Mugabe pe eni odun meta-le-ni-aadorun (93 years). Sibesibe, ko kuro ni ori aleefa.

Oro naa buru debi pe o ti n pete pero lati fi iyawo re, Grace Mugabe, je Aare ninu idibo to n bo.

Ni bayii ti awon ologun ti re e lepa, nje oro naa ko wa dabi ti ijapa tiroko, ekun oko yannibo to n lo sile ana re. Won bi i leere pe ojo wo lo maa de, o ni o di ojo ti oun ba te, ti oun fi ate tedii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…