Home Orisirisi O ma se o! Italy kuna lati lo si World Cup
Orisirisi - November 14, 2017

O ma se o! Italy kuna lati lo si World Cup

Ibanuje nla ti gba okan awon ololufe rere boolu ni orile-ede Italy bayii, latari bi egbe agbaboolu fun un  ti kuna lati pegede ninu idije ipalemo fun World Cup ti yoo waye ni Russia ni odun to n bo.

Ami ayo eyo kan soso ni Italy nilo ninu idije ikeyin to waye laarin awon ati Sweden.

Nigba ti won lo ba Sweden, iyen na won ni ami ayo kan si odo.

Sugbon ni orile-ede Italy ni ojo Monday, gbogbo agbara ni Italy sa, won ko ri okan soso naa da pada.

Pelu abajade naa, o tumo si pe won ko ni si ni World Cup, ni igba akoko lati odun 1958.

Bi a ko ba gbagbe, Italy lo fa ikuna ba Naijiria ni odun 1994, nigba ti egbe Green Eagles, to wa di Super Eagles bayii, tege de igbese keji ninu idije World Cup ti odun naa.

Asiko naa ni awon bii Rasidi Yekini ati Daniel Amokaci n se gudugudu meje ati yaayaa mefa fun Naija.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…