Home Orisirisi Buhari gba oyè ńlá méjì pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn ní Ebonyi
Orisirisi - November 14, 2017

Buhari gba oyè ńlá méjì pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn ní Ebonyi

Igba akoko niyi ti Aare Mohammadu Buhari maa se abewo si ile Igbo. Bi o se da ojo ni awon ajajagbara IPOB ti ni ko gbodo wa si agbegbe naa. Won ni ti o ba feran ara re, ki o ma se daa lasa lat wa si ile Igbo.

Aare Buhari ni, “ibi ti a ba ni ki gbegbe ma gbe ni gbegbe n gbe, ibi ti a ba si ni ki tete ma te ni tete n te”. Eyi lo mu ki Buhari ma se ka oro awon ajajagbara naa si rara.

Bi Aare se wo ipinle Ebonyi ni o ti bere si ni si awon ileese ni orisiirisii. Eyi to je pabanbari nibe ni oye nla kanka ti won fi daa lola. Won fun Buhari ni “Ochi Oha Ndigbo” to tumo si “Olori gbogbo wa”. Won tun fun un ni oye “Enyi Oma” to tumo si “ore gidi akoko”.

Won tun fun Aare ni baagi iresi Ebonyi egberun meji, egberun isu ati esin funfun balau to tumo si agbara isokan Ebonyi.Ti olori ti elemu lo pade Aare ni oni ojo kinni abewo naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…