Home Orisirisi Idi ti mo fi se MC nibi igbeyawo omo Saraki – Ali Baba
Orisirisi - November 9, 2017

Idi ti mo fi se MC nibi igbeyawo omo Saraki – Ali Baba

Gbajugbaja alawada, Ali Baba, ti se alaye idi ti oun fi se adari eto, ti a mo si master of ceremonies, nibi igbeyawo okan ninu awon omo Aare Ile Igbimo Asofin Agba, Dokita Bukola Saraki, to waye laipe yii.

Ali Baba so oro yii nigba ti awon kan bu enu ate lu u pe oun naa ti n ba awon alagbara jeun ita.

O ni enu ise oun ni oun wa. O ni ise ti oun n se kii se ise sorosoro nikan. O ni oun maa n ba awon eniyan se erongba lori ise won, bee, onisowo, iyen businessman, ni oun.

O ni loooto ni oun maa n soro si awon to ba n huwa ibaje lawujo, sugbon iyen ko ni ki oun ma sise oun bo ba ti yoju.

O ni awon ayaworan (photographers) wa nibi igbeyawo naa; awon olounje wa nibe, nigba ti awon olokowo miiran naa si lo sise oojo won nibe.

Ali Baba wa n bi awon to n bu enu ate lu u leere pee se wo ni oun se ti oun naa ba lo se ise aje toun nibi igbeyawo naa.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…