Home iroyin Awon eniyan f’aju ro nibi fidau omo Tinubu
iroyin - November 9, 2017

Awon eniyan f’aju ro nibi fidau omo Tinubu

Apeere pe nnkan ibanuje ni iku okan lara awon omo Asiwaju Bola Tinubu, iyen Jide Tinubu, je tun fara han nigba ti won se adura ojo kejo, ti awon Musulumi n pe ni Fidau, fun un ni Eko.

Opo awon eniyan to wa nibe lo f’aju ro, ti awon alaafaa si se waasi lori bi o se je pe dandan ni iku, ati pe oun to ba wu Olorun lo maa n fi eru re se lopo igba.

Gomina Ipinle Eko, Ogbeni Akinwunmi Ambode, awon to n ba a se ijoba, awon oloselu pataki pataki atiawon eniyan Asiwaju miiran lo wa nibe.

Ose to lo ni Tinubu ati iyawo re, Senito Oluremi Tinubu, lo si ilu oyinbo, leyin isele naa, tori ojoojumo ni awon eniyan n wo lo ki won ku airoju iku omo won naa.

Ki Olorun te Jide si afefe rere, ki o si ba wa mu owo iru re duro.

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…