Home iroyin A máa pààrọ̀ àwọn Tísà tí kò lè yege ìdánwò àwọn ọmọ ọlọ́dún kẹ́rin
iroyin - November 6, 2017

A máa pààrọ̀ àwọn Tísà tí kò lè yege ìdánwò àwọn ọmọ ọlọ́dún kẹ́rin

Ijoba ipinle Kaduna ni o ti na opolopo owo lori idanilekoo awon oluko ileewe alakoobere ti owo naa ko si yo. Bi ijoba naa se n nawo to ni awon omo ileewe n kuna to.

Eyi lo mu ki ijoba ipinle Kaduna se ipade pelu ajo awon oluko (NUT) ipinle naa ti gbogbo won fowo sii ki ijoba se idanwo fun awon oluko naa. Won pinnu lati se idanwo awon olodun kerin fun gbogbo oluko ile iwe alakoobere.

Oluko egberun metalelogbon (33,000) lo jokoo se idanwo naa. Ni igba ti esi idanwo jade, oluko egberun mokanla ati okoolelugba (11,220) lo yege idanwo naa ni igba ti awon to ku ko lee gba to maaki marundinlogorin ninu ida ogorun-un (75%).

Ijoba ipinle Kaduna pe ajo WAEC ati NECO pelu ifowo-sowo-po ile-iwe Fasiti Kaduna. Ijoba ipinle Kaduna salaye yii lati le ro arojare awon ti won ni ojoro wa ninu esi idanwo naa.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…