Home iroyin Buhari kò lè fi ọlọ́pàá mú ènìyàn – Femi Adesina
iroyin - November 1, 2017

Buhari kò lè fi ọlọ́pàá mú ènìyàn – Femi Adesina

Latari Babachir Lawal to je akowe agba fun ijoba apapo tele ati Ogbeni Ayodele Oke to je oga agba ni ileese National Intellegence Agency (NIA) tele ti ijoba apapo da duro lanaa, ni awon omo Naijiria ti n so ero won nipa idaduro naa.

Ki o to di wi pe ijoba apapo da won duro, ajo kan ti igbakeji Aare, Ojogbon Yemi Osinbajo dari ti dide si oro naa. Won pari ijiroro won lori won, won si gbe si iwaju Aare, pelu atotonu ati iwadii daadaa lori isele naa. Ijoba apapo da awon eniyan yii duro loju ese.

Ti a ko ba gbagba, Babachir ni o fi owo ti o to eniyan sola ge koriko nigba ti Ayodele Oke ni owo re ko mo nibi owo ile yii ati ti okeere ti won ka mo inu ile kan ni ilu Ikoyi to wa ni Eko.

Idaduro lasan awon eniyan ti owo won ko mo yii ko te awon omo Naijiria lorun, won ni o ye ki olopaa gbe won loju ese ki won si lo fi aso penpe roko oba.

Ogbeni Femi Adesina to je onimoran pataki lori iroyin si Aare ni agbara Aare ko kaa lati fi olopaa mu awon eniyan yii. Ibi ti agbara Aare mo ni ki o da won duro.

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…