Home iroyin Ọlọ́pàá yọ eyín asọ́bodè Immigration
iroyin - October 30, 2017

Ọlọ́pàá yọ eyín asọ́bodè Immigration

Ogbeni Roland Oibe ti ko ju omo odun mejilelogbon lo, to tun je osise asobode Immigration ni olopaa ti soo di ero ile-iwosan.

Jeje ni Roland n bo lati ibi to ti lo ra ounje fun akobi omo re ti iyawo re sese bi. O n lo pelu masinnin ti gbogbo aye mo si Okada, bi olopaa to wa ni oju ona se ju nnkan si enu masinnin re niyi. Roland gbe okiti, o si wọ nilẹ kuuruku. O fara pa yanna-yanna, kode agbọn bo, eyin si yọ si isẹlẹ naa.

Awon alaaanu oninu ọrẹ sare gbee lọ si ile-iwosan aladaani ki won to fi oro naa to awon ebi re leti. Ki awon ebi Roland to pada de ibi isele yii ni olopaa naa ti salọ. Ebi Roland ti fi oro naa to awon olopaa leti, won si fi ohun sile pe ajo olopaa ni lati mura sile lati san owo ile-iwosan naa.

Deede aago mejo ale ni isele naa sele ni adugbo kan ti won n pe ni Benson Abonu to wa ni ipinle Benue.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…