Home Orisirisi Awon omo Rashidi Yekini fe so ile baba won di SOCCER MUSEUM
Orisirisi - October 23, 2017

Awon omo Rashidi Yekini fe so ile baba won di SOCCER MUSEUM

Bi ina ba ku, a feeru oju; bi ogede ba ku, a fi omo re ropo.
Bee, won ni bi olode ko ku, ode baba eni ko hu gbegi.
Eyi lo difa fun awon omo agbaboolu agbayanu, Oloogbe Rashidi Yekini, ti won ti pinnu pea won yoo so ile baba awon to wa ni Ibadan di ile nnkan isenbaye fun ere boolu, iyen football museum.
Ile nla naa ti fee di jegejege, ti koriko si n kun mo o lara; se eeyan kuku ni ile.
Awon omo naa wa so pe dipo ti awon yoo fi maa wo o niran bee, o san ki awon gbe igbese oni ile nnkan isenbaye naa.
Loya Rashidi Yekini, Alagba Jubril Mohammed, ni o so erongba awon omo naa fun awon oniroyin.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìjàǹbá ọkọ̀ ní Fìdíwọ́ gbẹ̀mí èèyàn mẹ́fà láàrin ọ̀sẹ̀ kan

Ìjàǹbá ọkọ̀ ní Fìdíwọ́ gbẹ̀mí èèyàn mẹ́fà láàrin ọ̀sẹ̀ kan Ọrẹ Òtítọ́jù À fi kí Ọlọ́run má…