Home Orisirisi Ilé-ẹjọ́ ṣè’dájọ́ Boko Haram – Lai Mohammed
Orisirisi - October 18, 2017

Ilé-ẹjọ́ ṣè’dájọ́ Boko Haram – Lai Mohammed

Ile-ẹjọ giga t’o fikalẹ si Kanji, ipinlẹ Niger ti dajọ fi awọn ọmọ-ẹgbẹ Boko Haram marundinlaadọta si ẹwọn ọdun mẹta si ọdun mọkanlelọgbọn, lẹyin ipari ipele igbẹjọ akọkọ nigba ti a ṣe afihan awọn afurasi ọmọ-ẹgbẹ Boko Haram Ọrinlelẹgbẹta-din-marun-un.

Ninu atẹjade to jade ni Abuja ni ọjọ  ẹti, Minisita fun Aṣa ati Ilaniloyẹ, Alhaji Lai Mohammed sọ pe ile-ẹjọ da awọn afurasi ọtalenirinwo-o-le-mẹjọ, silẹ nitori wọn o ni ẹjọ dahun.

Ẹjọ awọn mẹrinlelọgbọn ni o yanju, nigba ti awọn afurasi mejidinlogbon wa ninu ahamọ, ti wọn yoo si wa jẹjọ ni Abuja ati Minna.

Ile-ẹjọ pa a laṣẹ pe ki awọn eniyan Ọtalelerinwo-o-le-mejo  ti wọn da silẹ, ki wọn ṣe eto ọpọlọ ati imu-pada-sipo-ironu fun wọn ki wọn to fa wọn le ijọba ipinlẹ ọkọọkan wọn lọwọ.

Igbẹjọ bẹrẹ pẹlu awọn afurasi Ọrinleleeedegbejọ-o-le-mẹsan-an ti ile-ejọ paṣẹ ki wọn wa  ni ahamọ fun aadọrun-un ọjọ, ni eyi ti ile-ẹjọ paṣẹ lati wa jẹjọ lasiko ti a ti fi fun wọn tabi ki a da wọn silẹ ni ai ni ohunkohun t’o ro mọ.

Ile-ẹjọ sun igbẹjọ awọn afurasi toku si Oṣu sẹẹre, ọdun to n bọ.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…