Home Orisirisi Idi ti mo fi fi Gani Adams je Aare Ona Kakanfo- Alaafin
Orisirisi - October 18, 2017

Idi ti mo fi fi Gani Adams je Aare Ona Kakanfo- Alaafin

 

Lati nnkan bii odun meta seyin, ohun kan pataki to wa lori emi Alaafin ti Oyo, Iku Baba Yeye, Oba Lamidi Adeyemi, ni yiyan Aare Ona Kakanfo miiran fun ile Yoruba.

Oloye MKO Abiola ni eni to je oye nla naa gbeyin, eni to ku ni odun mokandinlogun seyin.

Alaafin ati opo omo Yoruba miiran gba pe asiko ti to lati yan elomiiran.

Orisirisii nnkan ni awon eniyan ti so lori ta ni o ye ko won gbe ajaga nla naa le lori.

IROYIN OWURO si ti ko pupo nipa eyi.

Ni nnkan bii osu merin seyin ni  IROYIN OWURO ti gbo hulehule ohun ti Alaafin n wo mo eni ti a n wa lara.

Lona kinni, Kabiyesi ni eni naa gbodo ni ife Yoruba denu. Bee, ko gbodo je alagabagebe.

Iku Baba Yeye tun so pe eni naa gbodo je eni ti opo eniyan kaakiri Yoruba mo, ti won si mo riri ohun to ti se fun Omo Alade, to si setan lati se jubee lo.

Oba Adeyemi tun fi kun un pe eni naa gbodo gboju, ko gbonu, ko gboya, tori oye jagunjagun ni oye Aare Ona Kakanfo je.

Ni pataki, won tun ni o dara ki iru eni bee ni opo ero leyin. Ko gbodo je adanikan rin bii ti omo ejo. O gbodo je eni to je pe bi o ba pe eni kan, eniyan mewaa ni yoo da a lohun.

IROYIN OWURO wa gbo pe bi o tile je pe oruko oga awon egbe Odua People Congress, Oloye Gani Adams, wa lara awon to wa nita bayii, oun si tun n tesiwaju nipa jijiroro pelu awon lobaloba, nijoye-nijoye ati awon otokulu miiran ni.

Won si n wa eni to ba kaju kinni naa daadaa.

Bakan naa, Alaafin ti salye pe iwa akikanju ti Gani ni lo je ki oun gbe oye naa fun.

Kabiyesi ni Gani tun je eni kan to feran asa Yoruba, to si n sise fun idagbasoke re.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…