Home Orisirisi Gbogbo ayé ló yẹ kó gbógun ti IPOB – Lai Mohammed
Orisirisi - October 16, 2017

Gbogbo ayé ló yẹ kó gbógun ti IPOB – Lai Mohammed

Minisita fun iroyin ati asa ni Orileede yii, Alhaji Lai Mohammed lo se atejade yi ninu iwe iroyin ile Amerika “Washington Times” ni ojo Alamiisi to koja.

Minisita gba gbogbo omo Naijiria to wa nile ati ni oke okun ni iyanju lati gbogun ti awon ajajagbara ti won n fe orileede Biafra ni tipa-tipa. Lai Mohammed ni won soo ninu atejise won kan pe awon ko tile fe jijokoo so mo. Awon fe gba orileede ti awon ni tipa-tipa ni. Lara ohun ti Nnamidi Kanu to n siwaju ogun won so niyi “Ti won ba ko lati fun wa ni orileede Biafra. Somalia maa je paradise si ogba eranko ti won n pe ni Naijiria. A o tile ba enikankan jokoo mo, a fe gbaa pelu ibon ati gbogbo nnkan ija oloro miran”.

Minisita ni eyi lo faa ti ijoba apapo fi kede IPOB gege bi afipa-gbajoba bii ti ETA ti orileede Spain, Tamil Tigers ni Sri Lanka ati bii PKK ti orileede Turkey ti ajo ologun agbaye si gbogun ti won.

Lai Mohammed ni gbogbo ohun to ba gba ni ijoba apapo naa maa fun un lati ma se je ki awon ajo kan maa dun ikoko mo awon ara ilu.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…