Home Orisirisi Yegede! Gani Adams di AARE ONA KAKANFO Yoruba!
Orisirisi - October 15, 2017

Yegede! Gani Adams di AARE ONA KAKANFO Yoruba!

 

…Alaafin yoo gbe opa ase le e lowo

Lati Owo GBOTEMI OGUNYEMI

 

 

Isele idunnu kan ti se ni ile Yoruba bayii, latari bi Alaafin ti Oyo, Iku Baba Yeye, Oba Lamidi Adeyemi, se so Aare Egbe Oodua People’s Congress, Otunba Gani Adams, di Aare Ona Kakanfo Yoruba.

Oye naa ni oye Balogun-General fun gbogbo Kootu Ojiire, to si je pe oye nla ti awon akoni eniyan maa n je ni.

Lati odun 1998 ni ipo naa ti s’ofo, nigba ti Oloye MKO Abiola papoda; Abiola ni Are Ona Kakanfo to je leyin Oloye Ladoke Akintola.

Bi Gani Adams se di Aare Ona Kakanfo yii ti mu gbogbo ohun ti IROYIN OWURO ti ko seyin nipa oye nla naa se.

IROYIN OWURO ti se orisirisii iwadii ati afojusun lori t ni o ye ni Aare Ona Kakanfo miiran leyin iku Abiola.

A wa woye pe lara awon ti Alaafin le mu ni Asiwaju Bola Tinubu, Dokita Fredrick Fasheun, Otunba Gani Adams ati Omooba Olagunsoye Oyinlola.

Sugbon a gbo pea won akoni yii ko fi bee nifee si oye naa.

Bakan naa, ko jo pe eni kankan lara won wa ni ilana ti Alaafin ni lokan, nipa ohun ti Kabiyesi n wa lara eni to fe fi je oye yii.

Lara ohun ti Oba Adeyemi n wa lara Aare Ona Kakanfo ni eni ti o no eran jagunjagun lara; eni to ni opo eniyan leyin; eni ti okiki re si kan kaakiri ile Yoruba; to si tun je pe pun gan-an nifee lati je oye naa.

IROYIN OWURO ba Aaare lola Gani Adams soro lasaale yii, o si so pe bee ni oro ri pelu ogo Olorun.

A gbo pe Kabiyesi ti fi leta nla naa le Gani Adams lowo.

Kabiyesi ti fun Otunba Gani Adams ni leta, to si je pe laipe yii ni won yoo ja ewe oye le e lori.

Adura ti gbogbo wa yoo maa gba ni pe ki Olorun fun Aare tuntun ni alaafia ati emi gigun lati lo ipo naa fun ogo Yoruba.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…