Home LÁGBO ÀRÍYÁ Iku akufa laarin awon ore Davido: Ibanuje d’ori Omo Baba Olowo k’odo!
LÁGBO ÀRÍYÁ - October 11, 2017

Iku akufa laarin awon ore Davido: Ibanuje d’ori Omo Baba Olowo k’odo!

 

.Aye n fura pe oogun oloro lo seku pa ore Davido meta

Inu ibanuje nla ni Davido wa bayii, latari bi awon ore re bii meta, Tagbo, Chime ati DJ Olu, se iku ojiji tele ara won.

Ko pe ti awon ore naa jo se faaji tan ni wahala dede de ba won, ti won si di ero orun ka to seju pe.

Awon kan ni oti amuju lo fa wahala naa, ti awon kan si n so pe o seese ko je oogun oloro.

Sugbon awon olopaa ni bi o tile je pe awon dokita ti se ayewo ijinle, iyen autopsy, lori iku to pa Tagbo ati Chimey, won ko tii gbe esi re jade.

Won so eyi ni ifesi si ohun ti awon kan n so pe ayewo naa fihan pe oti amuju ati oogun oloro lo sokunfa adanu naa.

Inu Davido baje lori isele naa debi pe ibi ayeye odun Fela, iyen Felabration, to ye ko ti korin, ko lee lo sere nibe.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…