Home iroyin Naijiria nílò àtẹ isẹ́ ètò-ẹ̀kọ́ (Curriculum) míràn – Wale Omole
iroyin - October 11, 2017

Naijiria nílò àtẹ isẹ́ ètò-ẹ̀kọ́ (Curriculum) míràn – Wale Omole

Orileede Naijiria nilo atunto ate ise eto-eko miran bayii. Ojogbon Wale Omole to je olori tele ri ni Ifasiti to wa ni Ile-Ife, ni o n salaye yii nibi ayeye ogoji odun ti won da ile-iwe Chrisland sile.

Ojo weside ni ayeye naa waye ni Muson centre to wa ni Eko. Ibi ayeye naa ni gbogbo itan igbesi aye oludasile naa, Oloye agba, Winifred Awosika ti waye. Asiri bi ile-iwe naa se di araba naa jade ni ojo naa.

Ojogbon Omole ni ayafi ti a ba da ate ise eto-eko ti awon Oyinbo gbe bo wa lorun danu ni gbogbo nnkan to maa ni itumo to dara. O ni ede ajoji ni won fi gbe alaale naa fun wa, won si ni ki ede wa di eewo ni siso ni ile-iwe gbogbo. Ojogbon ni ibi ti isubu wa ti waye niyen. O ni bayii ti a ti dagba to oju bo, o ye ki a tun ate ise wa se ki a le ni ilosiwaju. A nilo ate to maa mu ki awon omo ile-iwe wa jade ile-iwe da ise se. A nilo ate to maa mu ki awon akekoo wa le danu ro. A nilo ate to le mu ki awon omo wa le gbe asa wa laruge ati bee bee lo.

Alaga ibi ayeye ifilole iwe eto eko igba yii ati ojo iwaju naa ni olori orileede yii tele ri, Oloye Ernest Shonekan nigba ti Ogagun ti oun naa ti je olori orileede yi ri tele, Ogagun Yakubu Gowon je alejo pataki sugbon Pasito Fred Odutola lo soju won. Idiat Adebule to je igbakeji gomina ipinle Eko ni Ajoke gbeleyi to je oga ile-iwe ajo aladaani soju.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…