Home iroyin Owó orí ṣekú pa Toyin l’Akurẹ
iroyin - October 10, 2017

Owó orí ṣekú pa Toyin l’Akurẹ

Adura ti opo osiise ijoba maa n gba ju ni “ki oko oba ati ada oba, ma se sa awon lese”. Adura awon osise ijoba meji ko gba ni ojo ti won lo gba owo ori lowo arabinrin kan to n je Toyin Ijiyemi. Ise aserunloge ni obinrin yi n se ni adugbo oke-aro ni ilu Akure.

Ni “ojo buruku esu gbomi mu” ti awon olowo ori lo si soobu re ni won ba beere owo ori Telifison re, o si n bebe pe oun ko tii san-an. Eyi bi awon olowo ori naa ninu pe, ofin ko fi aaye sile fun ebe, won fe maa gbe Telifison re lo. Ko fe gba fun won, won ba bere si ni jo duu mo ara won lowo. Ibe naa ni iroyin to te wa lowo ti ni arabinrin Toyin Ijiyemi jadi mole ti ko si dide mo.

Bi o tile je pe awon olowo ori naa ro pe o n dibon ni, won ko wo oju re, won kan gbe Telifison lo ni tiwon ni. Okan ninu awon to mu soobu ti oloogbe naa lo tete fariwo ta ki awon eniyan to gbe oku re lo si ile iwosan “Ondo State Specialists Hospital, Akure”.

Oloogbe Ijiyemi je Olorun nipe ni omo odun mejidinlogoji pere. Ki Eledua tee si afefe rere. Omo kan soso ti arabinrin naa fi saye, ogbeni Ayodele Adelanke ni ki omo Naijiria jowo ma se je ki iya naa je mama oun gbe, ki won fi oju asebi han, ki won si je iya to to si ese won.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…