Home Orisirisi Ede aiyede maa n waye laarin emi ati iyawo mi – Mike Bamiloye
Orisirisi - October 10, 2017

Ede aiyede maa n waye laarin emi ati iyawo mi – Mike Bamiloye

Gbajugbaja oni fiimu ti emi, Mike Bamiloye,  ti se alaye pe ede aiyede maa n waye laarin oun ati aya re, Gloria Bamidele leekokan.

Bi awon mejeeji se jo maa n se, paapaa niu fiimu, opo eniyan lo ro pe won kii jaa leekookan ni.

Sugbon nigba ti Mike Bamiloye n soro lori bi won se jo wa po fun odun mokandinlogbon gege bi loko-laya, o ni awon dupe lowo Olorun pe o fi oyin ati adun si igbeyawo awon, pelu awon omo to yan to yanju.

O ni aya rere ni Olorun fun oun, ti iyaafin naa, Gloria Bamiloye si so pe igbeyawo awon larinrin gidi ni.

Sugbon Mike Bamiloye ni leekookan, ede aiyede maa n wa ninu ile ati nigba ti awon ba n seto fiimu.

O ni bi eyi ba sewon a pe ara awon, awon a si soro nipa re, ti yoo si tan lokan kaluku awon.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…